Rom 4:1-25

Rom 4:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ kili awa o ha wipe Abrahamu, baba wa nipa ti ara, ri? Nitori bi a ba da Abrahamu lare nipa iṣẹ, o ni ohun iṣogo; ṣugbọn kì iṣe niwaju Ọlọrun. Iwe-mimọ́ ha ti wi? Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u. Njẹ fun ẹniti o ṣiṣẹ a kò kà ère na si ore-ọfẹ bikoṣe si gbese. Ṣugbọn fun ẹniti kò ṣiṣẹ, ti o si ngbà ẹniti o nda enia buburu lare gbọ́, a kà igbagbọ́ rẹ̀ si ododo. Gẹgẹ bi Dafidi pẹlu ti pe oluwarẹ̀ na ni ẹni ibukun, ẹniti Ọlọrun kà ododo si laisi ti iṣẹ́, Wipe, Ibukún ni fun awọn ẹniti a dari irekọja wọn jì, ti a si bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si li ọrùn. Ibukún yi ha jẹ ti awọn akọla nikan ni, tabi ti awọn alaikọla pẹlu? nitoriti a wipe, a kà igbagbọ́ fun Abrahamu si ododo. Bawo li a ha kà a si i? nigbati o wà ni ikọla tabi li aikọla? Kì iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni. O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu: Ati baba ikọla fun awọn ti kò si ninu kìki awọn akọla nikan, ṣugbọn ti nrin pẹlu nipasẹ igbagbọ́ Abrahamu baba wa, ti o ni li aikọla. Nitori ileri fun Abrahamu tabi fun irú-ọmọ rẹ̀ pe, on ó ṣe arole aiye, kì iṣe nipa ofin, bikoṣe nipa ododo igbagbọ́. Nitori bi awọn ti nṣe ti ofin ba ṣe arole, igbagbọ́ di asan, ileri si di alailagbara: Nitori ofin nṣiṣẹ́ ibinu: ṣugbọn nibiti ofin kò ba si, irufin kò si nibẹ̀. Nitorina li o fi ṣe ti ipa igbagbọ́, ki o le ṣe ti ipa ore-ọfẹ; ki ileri ki o le da gbogbo irú-ọmọ loju; kì iṣe awọn ti ipa ofin nikan, ṣugbọn ati fun awọn ti inu igbagbọ́ Abrahamu pẹlu, ẹniti iṣe baba gbogbo wa, (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Mo ti fi ọ ṣe baba orilẹ-ède pupọ,) niwaju ẹniti on gbagbọ́, Ọlọrun tikararẹ̀, ti o sọ okú di ãye, ti o si pè ohun wọnni ti kò si bi ẹnipe nwọn ti wà; Nigbati ireti kò si, ẹniti o gbagbọ ni ireti ki o le di baba orilẹ-ède pupọ, gẹgẹ bi eyi ti a ti wipe, Bayi ni irú-ọmọ rẹ yio ri. Ẹniti kò ṣe ailera ni igbagbọ́, kò rò ti ara on tikararẹ̀ ti o ti kú tan (nigbati o to bi ẹni ìwọn ọgọrun ọdún), ati kíku inu Sara: Kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ́, o nfi ogo fun Ọlọrun; Nigbati o sa ti mọ̀ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e. Nitorina li a si ṣe kà a si ododo fun u. A kò sá kọ ọ nitori tirẹ̀ nikan pe, a kà a si fun u, Ṣugbọn nitori tiwa pẹlu, ẹniti a o si kà a si fun, bi awa ba gbà a gbọ́, ẹniti o gbé Jesu Oluwa wa dide kuro ninu okú; Ẹniti a fi tọrẹ ẹ̀ṣẹ wa, ti a si jinde nitori idalare wa.

Rom 4:1-25 Yoruba Bible (YCE)

Kí ni kí á wí nípa Abrahamu baba-ńlá wa nípa ti ara? Kí ni ìrírí rẹ̀? Bí ó bá jẹ́ pé nítorí ohun tí ó ṣe ni Ọlọrun fi dá a láre, ìwọ̀nba ni ohun tí ó lè fi ṣe ìgbéraga. Ṣugbọn kò lè fọ́nnu níwájú Ọlọrun. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.” A kò lè pe èrè tí òṣìṣẹ́ bá gbà ní ẹ̀bùn; ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni. Ṣugbọn ẹni tí kò ṣe nǹkankan, ṣugbọn tí ó ṣá ní igbagbọ sí ẹni tí ó ń dá ẹni tí kò yẹ láre, Ọlọrun kà á sí ẹni rere nípa igbagbọ rẹ̀. Dafidi náà sọ̀rọ̀ nípa oríire ẹni tí Ọlọrun kà sí ẹni rere, láìwo iṣẹ́ tí ó ṣe. Ó ní, “Ẹni tí Ọlọrun bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì, tí Ọlọrun bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó ṣoríire. Ẹni tí Oluwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn sì ṣoríire.” Ṣé ẹni tí ó kọlà nìkan ni ó ṣoríire ni, tabi ati ẹni tí kò kọlà náà? Ohun tí a sọ ni pé, “Ọlọrun ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere fún Abrahamu.” Ipò wo ni ó wà tí Ọlọrun fi kà á sí ẹni rere: lẹ́yìn tí ó ti kọlà ni tabi kí ó tó kọlà? Kì í ṣe lẹ́yìn tí ó ti kọlà, kí ó tó kọlà ni. Ó gba àmì ìkọlà bí ẹ̀rí iṣẹ́ rere nípa igbagbọ tí ó ní nígbà tí kò ì tíì kọlà. Nítorí èyí, ó di baba fún gbogbo àwọn tí ó ní igbagbọ láì kọlà, kí Ọlọrun lè kà wọ́n sí ẹni rere; ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà. Nítorí kì í ṣe nítorí pé Abrahamu pa Òfin mọ́ ni Ọlọrun fi ṣe ìlérí fún òun ati ìran rẹ̀ pé yóo jogún ayé; nítorí ó gba Ọlọrun gbọ́ ni, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ń tẹ̀lé ètò Òfin ni yóo jogún ìlérí Ọlọrun, a jẹ́ pé ọ̀ràn àwọn tí ó dúró lórí igbagbọ di òfo, ìlérí Ọlọrun sì di òtúbáńtẹ́. Nítorí òfin ni ó ń mú ibinu Ọlọrun wá. Ṣugbọn níbi tí kò bá sí òfin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀. Ìdí nìyí tí ìlérí náà fi jẹ́ ti igbagbọ, kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́, kí ó sì lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbogbo ọmọ Abrahamu. Kì í ṣe fún àwọn tí ó gba ètò ti Òfin nìkan, bíkòṣe fún ẹni tí ó bá ní irú igbagbọ tí Abrahamu ẹni tí ó jẹ́ baba fún gbogbo wa ní. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo ti yàn ọ́ láti di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.” Níwájú Ọlọrun ni Abrahamu wà nígbà tí ó gba ìlérí yìí, níwájú Ọlọrun tí ó gbẹ́kẹ̀lé, Ọlọrun tí ó ń sọ òkú di alààyè, Ọlọrun tí ó ń pe àwọn ohun tí kò ì tíì sí jáde bí ẹni pé wọ́n wá. Abrahamu retí títí, ó gbàgbọ́ pé òun yóo di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti wí, pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo rí.” Igbagbọ rẹ̀ kò yẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ro ti ara rẹ̀ tí ó ti di òkú tán, (nítorí ó ti tó ẹni ọgọrun-un ọdún) ó tún ro ti Sara tí ó yàgàn. Kò fi aigbagbọ ṣiyèméjì sí ìlérí Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni igbagbọ rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i, ó fi ògo fún Ọlọrun nítorí pé ó dá a lójú pé ẹni tí ó ṣe ìlérí lè mú un ṣẹ. Ìdí rẹ̀ nìyí tí Ọlọrun fi ka igbagbọ rẹ̀ sí iṣẹ́ rere fún un. Ṣugbọn kì í ṣe nípa òun nìkan ṣoṣo ni a kọ ọ́ pé a ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere. A kọ ọ́ nítorí ti àwa náà tí a óo kà sí ẹni rere, gbogbo àwa tí a ní igbagbọ ninu ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde kúrò ninu òkú, ẹni tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde fún ìdáláre wa.

Rom 4:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Abrahamu, baba wa ti o ṣàwárí èyí? Májẹ̀mú láéláé jẹ́rìí sí i wí pé, a gba Abrahamu là nípa ìgbàgbọ́. Nítorí bí a bá dá Abrahamu láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ ha ti wí? “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.” Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ṣiṣẹ́, a kò ka èrè náà sí oore-ọ̀fẹ́ bí kò ṣe sí ẹ̀tọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo. Gẹ́gẹ́ bí Dafidi pẹ̀lú ti pe olúwa rẹ̀ náà ní ẹni ìbùkún, ẹni tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìsí ti iṣẹ́. Wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn.” Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Nítorí tí a wí pé, Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un. Báwo ni a ṣe kà á sí i? Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà? Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni. Ó sì gbé ààmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú. Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún nìkan, ṣùgbọ́n tiwọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Abrahamu ní, kí a tó kọ ọ́ nílà. Ìlérí fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀, ni pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́. Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá jẹ ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára: Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú: ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀. Nítorí náà ni ó ṣe gbé e ka orí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-ọ̀fẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú-ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Abrahamu, ẹni tí í ṣe baba gbogbo wa pátápátá, Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Mo ti fi ọ́ ṣe baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.” Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà. Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Abrahamu gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú-ọmọ rẹ̀ yóò rí.” Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó mọ pe ara òun tìkára rẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́ọ̀rún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sara: Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run; Pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀. Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe nítorí tirẹ̀ nìkan. Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú. A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jesu Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́. Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa.