Rom 3:23-25
Rom 3:23-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun; Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu: Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun
Rom 3:23-26 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí gbogbo eniyan ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun. Gbogbo wọn ni Ọlọrun ti ṣe lóore: ó dá wọn láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìràpadà tí Kristi Jesu ṣe. Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre.
Rom 3:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run: Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run