Rom 2:1-4
Rom 2:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA alairiwi ni iwọ ọkunrin na, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ ti ndajọ: nitori ninu ohun ti iwọ nṣe idajọ ẹlomiran, iwọ ndá ara rẹ lẹbi; nitori iwọ ti ndajọ nṣe ohun kanna. Ṣugbọn awa mọ̀ pe idajọ Ọlọrun jẹ gẹgẹ bi otitọ si gbogbo awọn ti o nṣe irú ohun bawọnni. Ati iwọ ọkunrin na ti nṣe idajọ awọn ti nṣe irú ohun bawọnni, ti iwọ si nṣe bẹ̃ na, iwọ ro eyi pe iwọ ó yọ ninu idajọ Ọlọrun? Tabi iwọ ngàn ọrọ̀ ore ati ipamọra ati sũru rẹ̀, li aimọ̀ pe ore Ọlọrun li o nfà ọ lọ si ironupiwada?
Rom 2:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Kò sí àwáwí kankan fún ọ, ìwọ tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. Nǹkan gan-an tí ò ń torí rẹ̀ dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́ ni o fi ń dá ara rẹ lẹ́bi. Nítorí ìwọ náà tí ò ń dáni lẹ́jọ́ ń ṣe àwọn nǹkan gan-an tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́bi fún. Ṣugbọn a mọ̀ pé Ọlọrun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi. Ìwọ tí ò ń dá àwọn ẹlòmíràn tí ó ń ṣe nǹkan wọnyi lẹ́jọ́, tí ìwọ alára sì ń ṣe nǹkankan náà, ṣé o wá rò pé ìwọ óo bọ́ ninu ìdájọ́ Ọlọrun ni? Àbí o fi ojú tẹmbẹlu ọpọlọpọ oore Ọlọrun ni, ati ìfaradà rẹ̀ ati sùúrù rẹ̀? O kò mọ̀ pé kí o lè ronupiwada ni gbogbo oore tí Ọlọrun ń ṣe
Rom 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dá ni lẹ́jọ́: nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dá ni lẹ́jọ́. Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ si gbogbo àwọn tí ó ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí. Nítorí bí ìwọ tí ń ṣe ènìyàn lásán bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí, tí ìwọ tìkára rẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ro èyí pé ìwọ o yọ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí? Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀? Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà?