Rom 15:4-13

Rom 15:4-13 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí fún àtikọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ni a ṣe kọ ohunkohun tí a ti kọ tẹ́lẹ̀, ìdí rẹ̀ ni pé kí ìgboyà ati ìwúrí tí Ìwé Mímọ́ ń fún wa lè fún wa ní ìrètí. Kí Ọlọrun, tí ó ń fún wa ní ìrọ́jú ati ìwúrí, jẹ́ kí ẹ ní ọkàn kan náà sí ara yín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Kristi Jesu, kí ẹ fi inú kan ati ohùn kan yin Ọlọrun ati Baba Oluwa Jesu Kristi. Nítorí náà, ẹ fa ara yín mọ́ra gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà yín, kí á lè fi ògo fún Ọlọrun. Ohun tí mò ń sọ ni pé Kristi ti di iranṣẹ fún àwọn tí ó kọlà, láti mú òtítọ́ Ọlọrun ṣẹ, kí ó lè mú àwọn ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba-ńlá ṣẹ, ati láti jẹ́ kí àwọn tí kò kọlà lè yin Ọlọrun nítorí àánú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí èyí, n óo yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo kọrin sí orúkọ rẹ.” Ó tún sọ pé, “Ẹ bá àwọn eniyan rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè.” Ó tún sọ pé, “Ẹ yin Oluwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè kí gbogbo eniyan yìn ín.” Aisaya tún sọ pé, “Gbòǹgbò kan yóo ti ìdílé Jese yọ, yóo yọ láti pàṣẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí àwọn orílẹ̀-èdè wà.” Kí Ọlọrun tí ó ń fúnni ní ìrètí fi ayọ̀ tí ò kún ati alaafia fun yín nípa igbagbọ yín, kí ẹ lè máa dàgbà ninu ìrètí tí ẹ ní ninu Ẹ̀mí Mímọ́.

Rom 15:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí ohun gbogbo tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ láti fi kọ́ wa pé, nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́, kí àwa lè ní ìrètí. Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin láti ní inú kan sí ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jesu Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jesu Kristi. Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run. Mo sì wí pé, a rán Kristi láti ṣe ìránṣẹ́ ìkọlà àwọn tí ṣe Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀, kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí, Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.” Ó sì tún wí pé, “Ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí; ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.” Isaiah sì tún wí pé, “Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá, òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí; Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.” Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

Rom 15:4-13

Rom 15:4-13 YBCVRom 15:4-13 YBCVRom 15:4-13 YBCVRom 15:4-13 YBCVRom 15:4-13 YBCVRom 15:4-13 YBCVRom 15:4-13 YBCV