Rom 12:9-18
Rom 12:9-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki ifẹ ki o wà li aiṣẹtan. Ẹ mã takéte si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ́ ohun ti iṣe rere. Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju. Niti iṣẹ ṣiṣe, ẹ má ṣe ọlẹ; ẹ mã ni igbona ọkàn; ẹ mã sìn Oluwa; Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura; Ẹ mã pese fun aini awọn enia mimọ́; ẹ fi ara nyin fun alejò iṣe. Ẹ mã súre fun awọn ti nṣe inunibini si nyin: ẹ mã sure, ẹ má si ṣepè. Awọn ti nyọ̀, ẹ mã ba wọn yọ̀, awọn ti nsọkun, ẹ mã ba wọn sọkun. Ẹ mã wà ni inu kanna si ara nyin. Ẹ máṣe tọju ohun gíga, ṣugbọn ẹ mã tẹle awọn onirẹlẹ. Ẹ máṣe jẹ ọlọ́gbọn li oju ara nyin. Ẹ máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni. Ẹ mã pèse ohun ti o tọ́ niwaju gbogbo enia. Bi o le ṣe, bi o ti wà ni ipa ti nyin, ẹ mã wà li alafia pẹlu gbogbo enia.
Rom 12:9-18 Yoruba Bible (YCE)
Ìfẹ́ yín kò gbọdọ̀ ní ẹ̀tàn ninu. Ẹ kórìíra nǹkan burúkú. Ẹ fara mọ́ àwọn nǹkan rere. Ẹ ní ìfẹ́ láàrin ara yín bíi mọ̀lẹ́bí. Ní ti bíbu ọlá fún ara yín, ẹ máa fi ti ẹnìkejì yín ṣiwaju. Ẹ má jẹ́ kí ìtara yín rẹ̀yìn. Ẹ máa sin Oluwa tọkàntọkàn. Ẹ máa yọ̀ nítorí ìrètí tí ẹ ní. Ẹ máa fara da ìṣòro, kí ẹ sì tẹra mọ́ adura. Ẹ pín àwọn aláìní láàrin àwọn onigbagbọ ninu ohun ìní yín. Ẹ máa ṣaájò àwọn àlejò. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń ṣe inúnibíni yín, kàkà kí ẹ ṣépè, ìre ni kí ẹ máa sú fún wọn. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sunkún, ẹ bá wọn sunkún. Ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ má ṣe gbèrò ohun gíga-gíga, ṣugbọn ẹ máa darapọ̀ mọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín. Ẹ má máa fi burúkú san burúkú. Ẹ jẹ́ kí èrò ọkàn yín sí gbogbo eniyan máa jẹ́ rere. Ẹ sa ipá yín, níwọ̀n bí ó bá ti ṣeéṣe, láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu gbogbo eniyan.
Rom 12:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe. Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún. Ẹ máa wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe gbéraga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.