Rom 12:6-12
Rom 12:6-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ bi awa si ti nri ọ̀tọ ọ̀tọ ẹ̀bun gbà gẹgẹ bi ore-ọfẹ ti a fifun wa, bi o ṣe isọtẹlẹ ni, ki a mã sọtẹlẹ gẹgẹ bi ìwọn igbagbọ́; Tabi iṣẹ-iranṣẹ, ki a kọjusi iṣẹ-iranṣẹ wa: tabi ẹniti nkọ́ni, ki o kọjusi kíkọ́; Tabi ẹniti o ngbàni niyanju, si igbiyanju: ẹniti o nfi funni ki o mã fi inu kan ṣe e; ẹniti nṣe olori, ki o mã ṣe e li oju mejeji; ẹniti nṣãnu, ki o mã fi inu didùn ṣe e. Ki ifẹ ki o wà li aiṣẹtan. Ẹ mã takéte si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ́ ohun ti iṣe rere. Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju. Niti iṣẹ ṣiṣe, ẹ má ṣe ọlẹ; ẹ mã ni igbona ọkàn; ẹ mã sìn Oluwa; Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura
Rom 12:6-12 Yoruba Bible (YCE)
Bí a ti ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pín oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí á lò wọ́n. Bí ẹnìkan bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, kí ó lò ó gẹ́gẹ́ bí igbagbọ rẹ̀ ti mọ. Bí ó bá jẹ́ ẹ̀bùn láti darí ètò ni, kí á lò ó láti darí ètò. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, kí ó lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí ó bá ní ẹ̀bùn láti fúnni ní ọ̀rọ̀ ìwúrí, kí ó lò ó láti lé ìrẹ̀wẹ̀sì jìnnà. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, kí ó ṣe é pẹlu ọkàn kan. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn láti ṣe aṣiwaju, kí ó ṣe é tọkàntọkàn. Ẹni tí ó bá ń ṣiṣẹ́ àánú, kí ó fọ̀yàyà ṣe é. Ìfẹ́ yín kò gbọdọ̀ ní ẹ̀tàn ninu. Ẹ kórìíra nǹkan burúkú. Ẹ fara mọ́ àwọn nǹkan rere. Ẹ ní ìfẹ́ láàrin ara yín bíi mọ̀lẹ́bí. Ní ti bíbu ọlá fún ara yín, ẹ máa fi ti ẹnìkejì yín ṣiwaju. Ẹ má jẹ́ kí ìtara yín rẹ̀yìn. Ẹ máa sin Oluwa tọkàntọkàn. Ẹ máa yọ̀ nítorí ìrètí tí ẹ ní. Ẹ máa fara da ìṣòro, kí ẹ sì tẹra mọ́ adura.
Rom 12:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é. Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà.