Rom 12:5-8
Rom 12:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃li awa, ti a jẹ́ pipọ, a jẹ́ ara kan ninu Kristi, ati olukuluku ẹ̀ya ara ọmọnikeji rẹ̀. Njẹ bi awa si ti nri ọ̀tọ ọ̀tọ ẹ̀bun gbà gẹgẹ bi ore-ọfẹ ti a fifun wa, bi o ṣe isọtẹlẹ ni, ki a mã sọtẹlẹ gẹgẹ bi ìwọn igbagbọ́; Tabi iṣẹ-iranṣẹ, ki a kọjusi iṣẹ-iranṣẹ wa: tabi ẹniti nkọ́ni, ki o kọjusi kíkọ́; Tabi ẹniti o ngbàni niyanju, si igbiyanju: ẹniti o nfi funni ki o mã fi inu kan ṣe e; ẹniti nṣe olori, ki o mã ṣe e li oju mejeji; ẹniti nṣãnu, ki o mã fi inu didùn ṣe e.
Rom 12:5-8 Yoruba Bible (YCE)
bẹ́ẹ̀ gan-an ni gbogbo wa, bí á tilẹ̀ pọ̀, ara kan ni wá ninu Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sì jẹ́ ẹ̀yà ara ẹnìkejì rẹ̀. Bí a ti ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pín oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí á lò wọ́n. Bí ẹnìkan bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, kí ó lò ó gẹ́gẹ́ bí igbagbọ rẹ̀ ti mọ. Bí ó bá jẹ́ ẹ̀bùn láti darí ètò ni, kí á lò ó láti darí ètò. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, kí ó lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí ó bá ní ẹ̀bùn láti fúnni ní ọ̀rọ̀ ìwúrí, kí ó lò ó láti lé ìrẹ̀wẹ̀sì jìnnà. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, kí ó ṣe é pẹlu ọkàn kan. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn láti ṣe aṣiwaju, kí ó ṣe é tọkàntọkàn. Ẹni tí ó bá ń ṣiṣẹ́ àánú, kí ó fọ̀yàyà ṣe é.
Rom 12:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.