Rom 11:29-32
Rom 11:29-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ailábámọ̀ li ẹ̀bun ati ipe Ọlọrun. Nitori gẹgẹ bi ẹnyin kò ti gbà Ọlọrun gbọ́ ri, ṣugbọn nisisiyi ti ẹnyin ri ãnu gbà nipa aigbagbọ́ wọn: Gẹgẹ bẹ̃li awọn wọnyi ti o ṣe aigbọran nisisiyi, ki awọn pẹlu ba le ri ãnu gbà nipa ãnu ti a fi hàn nyin. Nitori Ọlọrun sé gbogbo wọn mọ pọ̀ sinu aigbagbọ́, ki o le ṣãnu fun gbogbo wọn.
Rom 11:29-32 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí Ọlọrun kò jẹ́ kábàámọ̀ pé òun fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn kí ó wá gbà á pada. Bí ẹ̀yin fúnra yín ti jẹ́ aláìgbọràn sí Ọlọrun nígbà kan rí, ṣugbọn tí ó wá ṣàánú yín nígbà tí àwọn Juu ṣàìgbọràn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nisinsinyii tí ẹ̀yin náà rí àánú gbà, wọ́n di aláìgbọràn, kí àwọn náà lè rí àánú Ọlọrun gbà. Nítorí Ọlọrun ti ka gbogbo eniyan sí ẹlẹ́bi nítorí àìgbọràn wọn, kí ó lè ṣàánú fún gbogbo wọn papọ̀.
Rom 11:29-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí àìlábámọ̀ ni ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí àánú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí tí ó ṣe àìgbọ́ràn nísinsin yìí, kí àwọn pẹ̀lú bá le rí àánú gbà nípa àánú tí a fihàn yín. Nítorí Ọlọ́run sé gbogbo wọn mọ́ pọ̀ sínú àìgbàgbọ́, kí ó le ṣàánú fún gbogbo wọn.