Rom 10:9-13
Rom 10:9-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là. Nitori ọkàn li a fi igbagbọ́ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala. Nitori iwe-mimọ́ wipe, Ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ oju ki yio ti i. Nitori kò si ìyatọ ninu Ju ati Hellene: nitori Oluwa kanna l'Oluwa gbogbo wọn, o si pọ̀ li ọrọ̀ fun gbogbo awọn ti nkepè e. Nitori ẹnikẹni ti o ba sá pè orukọ, Oluwa, li a o gbàlà.
Rom 10:9-13 Yoruba Bible (YCE)
bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ pé, “Jesu ni Oluwa,” tí o sì gbàgbọ́ lọ́kàn rẹ pé Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú, a óo gbà ọ́ là. Nítorí pẹlu ọkàn ni a fi ń gbàgbọ́ láti rí ìdáláre gbà. Ṣugbọn ẹnu ni a fi ń jẹ́wọ́ láti rí ìgbàlà. Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ tí ojú yóo tì.” Nítorí kò sí ìyàtọ̀ kan láàrin Juu ati Giriki. Nítorí Ọlọrun kan náà ni Oluwa gbogbo wọn, ọlá rẹ̀ sì pọ̀ tó fún gbogbo àwọn tí ó bá ń ké pè é. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.”
Rom 10:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là. Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà. Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”