Rom 10:6-11
Rom 10:6-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ododo ti iṣe ti igbagbọ́ sọ bayi pe, Máṣe wi li ọkàn rẹ pe, tani yio goke lọ si ọrun? (eyini ni, lati mu Kristi sọkalẹ:) Tabi, tani yio sọkalẹ lọ si ọgbun? (eyini ni, lati mu Kristi goke ti inu okú wá). Ṣugbọn kili o wi? Ọ̀rọ na wà leti ọdọ rẹ, li ẹnu rẹ, ati li ọkan rẹ: eyini ni, ọ̀rọ igbagbọ́, ti awa nwasu; Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là. Nitori ọkàn li a fi igbagbọ́ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala. Nitori iwe-mimọ́ wipe, Ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ oju ki yio ti i.
Rom 10:6-11 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn báyìí ni Ìwé Mímọ́ wí nípa ìdáláre tí à ń gbà nípa igbagbọ, pé, “Má ṣe wí ní ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóo gòkè lọ sọ́run?’ ” (Èyí ni láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀.) “Tabi, ‘Ta ni yóo wọ inú ọ̀gbun ilẹ̀ lọ?’ ” (Èyí ni, láti mú Kristi jáde kúrò láàrin àwọn òkú.) Ṣugbọn ohun tí ó sọ ni pé, “Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, àní, ó wà lẹ́nu rẹ ati lọ́kàn rẹ.” Èyí ni ọ̀rọ̀ igbagbọ tí à ń waasu, pé: bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ pé, “Jesu ni Oluwa,” tí o sì gbàgbọ́ lọ́kàn rẹ pé Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú, a óo gbà ọ́ là. Nítorí pẹlu ọkàn ni a fi ń gbàgbọ́ láti rí ìdáláre gbà. Ṣugbọn ẹnu ni a fi ń jẹ́wọ́ láti rí ìgbàlà. Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ tí ojú yóo tì.”
Rom 10:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀) “tàbí, ta ni yóò sọ̀kalẹ̀ lọ si ọ̀gbun?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi gòkè ti inú òkú wá). Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù; Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là. Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà. Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.”