Rom 10:11-14
Rom 10:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori iwe-mimọ́ wipe, Ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ oju ki yio ti i. Nitori kò si ìyatọ ninu Ju ati Hellene: nitori Oluwa kanna l'Oluwa gbogbo wọn, o si pọ̀ li ọrọ̀ fun gbogbo awọn ti nkepè e. Nitori ẹnikẹni ti o ba sá pè orukọ, Oluwa, li a o gbàlà. Njẹ nwọn o ha ti ṣe kepe ẹniti nwọn kò gbagbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbà ẹniti nwọn kò gburó rẹ̀ rí gbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbọ́ laisi oniwasu?
Rom 10:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ tí ojú yóo tì.” Nítorí kò sí ìyàtọ̀ kan láàrin Juu ati Giriki. Nítorí Ọlọrun kan náà ni Oluwa gbogbo wọn, ọlá rẹ̀ sì pọ̀ tó fún gbogbo àwọn tí ó bá ń ké pè é. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” Ṣugbọn báwo ni wọn yóo ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ gbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gbúròó rẹ̀ láìsí àwọn tí ó ń kéde rẹ̀?
Rom 10:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.” Ǹjẹ́ wọn ó ha ti ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o ha sì ti ṣe gbọ́ láìsí oníwàásù?