Ifi 8:10-11
Ifi 8:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Angẹli kẹta si fun, irawọ̀ nla kan ti njo bi fitila si bọ́ lati ọrun wá, o si bọ sori idamẹta awọn odo ṣiṣàn, ati sori awọn orisun omi; A si npè orukọ irawọ na ni Iwọ idamẹta: awọn omi si di iwọ, ọ̀pọlọpọ enia si ti ipa awọn omi na kú, nitoriti a sọ wọn di kikorò.
Ifi 8:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Angẹli kẹta fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá kan bá já bọ́ láti ọ̀run. Ó bẹ̀rẹ̀ sí jóná bí ògùṣọ̀. Ó bá já sinu ìdámẹ́ta àwọn odò ati ìsun omi. Orúkọ ìràwọ̀ náà ni “Igi-kíkorò.” Ó mú kí ìdámẹ́ta omi korò, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó sì kú nítorí oró tí ó wà ninu omi.
Ifi 8:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Angẹli kẹta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ́ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi; A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ, ìdámẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.