Ifi 7:15-16
Ifi 7:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ni nwọn ṣe mbẹ niwaju itẹ́ Ọlọrun, ti nwọn si nsìn i li ọsán ati li oru ninu tẹmpili rẹ̀: ẹniti o joko lori itẹ́ na yio si ṣiji bò wọn. Ebi kì yio pa wọn mọ́, bẹ̃li ongbẹ kì yio gbẹ wọn mọ́; bẹ̃li õrùn kì yio pa wọn tabi õrukõru.
Ifi 7:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí èyí ni wọ́n ṣe wà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun, tí wọn ń júbà tọ̀sán-tòru ninu Tẹmpili rẹ̀. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà yóo máa bá wọn gbé. Ebi kò ní pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kò ní gbẹ wọ́n mọ́. Oòrùn kò ní pa wọ́n mọ́, ooru kankan kò sì ní mú wọn mọ́.
Ifi 7:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà ni, “wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀; ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si ṣíji bò wọn. Ebi kì yóò pa wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́; bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn tàbí oorukóoru kan.