Ifi 5:1-10

Ifi 5:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)

MO si ri li ọwọ́ ọtún ẹniti o joko lori itẹ́ na, iwe kan ti a kọ ninu ati lẹhin, ti a si fi èdidi meje dì. Mo si ri angẹli alagbara kan, o nfi ohùn rara kede pe, Tali o yẹ lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀? Kò si si ẹnikan li ọrun, tabi lori ilẹ aiye, tabi nisalẹ ilẹ, ti o le ṣí iwe na, tabi ti o le wò inu rẹ̀. Emi si sọkun gidigidi, nitoriti a kò ri ẹnikan ti o yẹ lati ṣí ati lati kà iwe na, tabi lati wò inu rẹ̀. Ọkan ninu awọn àgba na si wi fun mi pe, Máṣe sọkun: kiyesi i, Kiniun ẹ̀ya Juda, Gbòngbo Dafidi, ti bori lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀ mejẽje. Mo si ri li arin itẹ́ na, ati awọn ẹda alãye mẹrin na, ati li arin awọn àgba na, Ọdọ-Agutan kan duro bi eyiti a ti pa, o ni iwo meje ati oju meje, ti iṣe Ẹmí meje ti Ọlọrun, ti a rán jade lọ si ori ilẹ aiye gbogbo. O si wá, o si gbà a li ọwọ́ ọtún ẹniti o joko lori itẹ́ na. Nigbati o si gbà iwe na, awọn ẹda alãye mẹrin na, ati awọn àgba mẹrinlelogun na wolẹ niwaju Ọdọ-Agutan na, olukuluku nwọn ní dùru ati ago wura ti o kún fun turari ti iṣe adura awọn enia mimọ́. Nwọn si nkọ orin titun kan, wipe, Iwọ li o yẹ lati gbà iwe na, ati lati ṣí èdidi rẹ̀: nitoriti a ti pa ọ, iwọ si ti fi ẹ̀jẹ rẹ ṣe ìrapada enia si Ọlọrun lati inu ẹyà gbogbo, ati ède gbogbo, ati inu enia gbogbo, ati orilẹ-ède gbogbo wá; Iwọ si ti ṣe wọn li ọba ati alufa si Ọlọrun wa: nwọn si njọba lori ilẹ aiye.

Ifi 5:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, mo rí ìwé kan ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́: wọ́n kọ nǹkan sí i ninu ati lóde, wọ́n sì fi èdìdì meje dì í. Mo sì rí angẹli alágbára kan tí ń ké pẹlu ohùn rara pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, ati láti tú èdìdì rẹ̀?” Kò sí ẹnikẹ́ni ní ọ̀run, tabi lórí ilẹ̀ tabi nísàlẹ̀ ilẹ̀ tí ó lè ṣí ìwé náà tabi tí ó lè wò ó. Mo sunkún lọpọlọpọ nítorí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ láti ṣí ìwé náà ati láti wò ó. Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí wá sọ fún mi pé, “Má sunkún mọ́! Wò ó! Kinniun ẹ̀yà Juda, ọmọ Dafidi, ti borí. Ó le ṣí ìwé náà ó sì le tú èdìdì meje tí a fi dì í.” Mo bá rí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó dúró láàrin ìtẹ́ náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà yí i ká. Ọ̀dọ́ Aguntan náà dàbí ẹni pé wọ́n ti pa á. Ìwo meje ni ó ní ati ojú meje. Àwọn ojú meje yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje tí Ọlọrun rán sí gbogbo orílẹ̀ ayé. Ọ̀dọ́ Aguntan náà bá wá, ó sì gba ìwé náà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ. Wọ́n wá ń kọ orin titun kan, pé, “Ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ìwé náà, ati láti tú èdìdì ara rẹ̀. Nítorí wọ́n pa ọ́, o sì ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ bá Ọlọrun ṣe ìràpadà eniyan, láti inú gbogbo ẹ̀yà, ati gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè. O ti sọ wọ́n di ìjọba ti alufaa láti máa sin Ọlọrun wa. Wọn yóo máa jọba ní ayé.”

Ifi 5:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí. Mó sì rí angẹli alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀?” Kò sì ṣí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀. Èmi sì sọkún gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.” Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo. Ó sì wá, o sì gbà á ìwé náà ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà. Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú ohun èlò orin olókùn kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́. Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé: “Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà, àti láti ṣí èdìdì rẹ̀: nítorí tí a tí pa ọ, ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo, àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá: Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá: wọ́n sì ń jẹ ọba lórí ilẹ̀ ayé.”