Ifi 3:17-18
Ifi 3:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoriti iwọ wipe, Emi li ọrọ̀, emi si npọ̀ si i li ọrọ̀, emi kò si ṣe alaini ohunkohun; ti iwọ kò si mọ̀ pe, òṣi ni iwọ, ati àre, ati talakà, ati afọju, ati ẹni-ìhoho: Emi fun ọ ni ìmọran pe ki o rà wura lọwọ mi ti a ti dà ninu iná, ki iwọ ki o le di ọlọ́rọ̀; ati aṣọ funfun, ki iwọ ki o le fi wọ ara rẹ, ati ki itiju ìhoho rẹ ki o má bã hàn, ki o si fi õgùn kùn oju rẹ, ki iwọ ki o le riran.
Ifi 3:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ò ń sọ pé: Mo lówó, mo lọ́rọ̀. Kò sí ohun tí mo fẹ́ tí n kò ní. O kò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ tí eniyan ń káàánú ni ọ́, òtòṣì afọ́jú tí ó wà ní ìhòòhò. Mo dá ọ nímọ̀ràn pé kí o ra wúrà tí wọ́n ti dà ninu iná lọ́wọ́ mi, kí o lè ní ọrọ̀, kí o ra aṣọ funfun kí o fi bora, kí ìtìjú ìhòòhò tí o wà má baà hàn, sì tún ra òògùn ojú, kí o fi sí ojú rẹ kí o lè ríran.
Ifi 3:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò: Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.