Ifi 3:14-19
Ifi 3:14-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati si angẹli ijọ ni Laodikea kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti ijẹ Amin wi, ẹlẹri olododo ati olõtọ, olupilẹṣẹ ẹda Ọlọrun. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, pe iwọ kò gbóna bẹ̃ni iwọ kò tutù: emi iba fẹ pe ki iwọ kuku tutù, tabi ki iwọ kuku gbóna. Njẹ nitoriti iwọ ṣe ìlọ́wọwọ, ti o kò si gbóna, bẹni o kò tutù, emi o pọ̀ ọ jade kuro li ẹnu mi. Nitoriti iwọ wipe, Emi li ọrọ̀, emi si npọ̀ si i li ọrọ̀, emi kò si ṣe alaini ohunkohun; ti iwọ kò si mọ̀ pe, òṣi ni iwọ, ati àre, ati talakà, ati afọju, ati ẹni-ìhoho: Emi fun ọ ni ìmọran pe ki o rà wura lọwọ mi ti a ti dà ninu iná, ki iwọ ki o le di ọlọ́rọ̀; ati aṣọ funfun, ki iwọ ki o le fi wọ ara rẹ, ati ki itiju ìhoho rẹ ki o má bã hàn, ki o si fi õgùn kùn oju rẹ, ki iwọ ki o le riran. Gbogbo awọn ti emi ba fẹ ni mo mbawi, ti mo si nnà: nitorina ni itara, ki o si ronupiwada.
Ifi 3:14-19 Yoruba Bible (YCE)
“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Laodikia pé: “Ẹni tí ń jẹ́ Amin, olóòótọ́ ati ẹlẹ́rìí òdodo, alákòóso ẹ̀dá Ọlọrun ní Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ̀ pé o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù. Ninu kí o gbóná tabi kí o tutù, ó yẹ kí o ṣe ọ̀kan. Nítorí pé o lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ lásán, o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù, n óo pọ̀ ọ́ jáde lẹ́nu mi. Nítorí ò ń sọ pé: Mo lówó, mo lọ́rọ̀. Kò sí ohun tí mo fẹ́ tí n kò ní. O kò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ tí eniyan ń káàánú ni ọ́, òtòṣì afọ́jú tí ó wà ní ìhòòhò. Mo dá ọ nímọ̀ràn pé kí o ra wúrà tí wọ́n ti dà ninu iná lọ́wọ́ mi, kí o lè ní ọrọ̀, kí o ra aṣọ funfun kí o fi bora, kí ìtìjú ìhòòhò tí o wà má baà hàn, sì tún ra òògùn ojú, kí o fi sí ojú rẹ kí o lè ríran. Àwọn tí mo bá fẹ́ràn ni mò ń bá wí, àwọn ni mò ń tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ní ìtara, kí o sì ronupiwada.
Ifi 3:14-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé: Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run: Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù: èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná. Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi. Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò: Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran. Gbogbo àwọn ti èmi bá fẹ́ ni èmi ń bá wí, tí mo sì ń nà: nítorí náà, ní ìtara, kì ìwọ sì ronúpìwàdà.