Ifi 3:12
Ifi 3:12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti o ba ṣẹgun, on li emi o fi ṣe ọwọ̀n ninu tẹmpili Ọlọrun mi, on kì yio si jade kuro nibẹ mọ́: emi o si kọ orukọ Ọlọrun mi si i lara, ati orukọ ilu Ọlọrun mi, ti iṣe Jerusalemu titun, ti o nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun mi wá, ati orukọ titun ti emi tikarami.
Ifi 3:12 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fi ṣe òpó ninu Tẹmpili Ọlọrun mi. Kò ní kúrò níbẹ̀ mọ́. N óo wá kọ orúkọ Ọlọrun mi ati orúkọ mi titun sí i lára, ati ti Jerusalẹmu titun, ìlú Ọlọrun mi, tí ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun mi.
Ifi 3:12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́: èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi.