Ifi 21:22-27
Ifi 21:22-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi kò si ri tẹmpili ninu rẹ̀: nitoripe Oluwa Ọlọrun Olodumare ni tẹmpili rẹ̀, ati Ọdọ-Agutan. Ilu na kò si ni iwá õrùn, tabi oṣupa, lati mã tan imọlẹ si i: nitoripe ogo Ọlọrun li o ntàn imọlẹ si i, Ọdọ-Agutan si ni fitila rẹ̀. Awọn orilẹ-ède yio si mã rìn nipa imọlẹ rẹ̀: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wá sinu rẹ̀. A kì yio si sé awọn ẹnubode rẹ̀ rara li ọsán: nitori kì yio si oru nibẹ̀. Nwọn o si ma mu ogo ati ọlá awọn orilẹ-ède wá sinu rẹ̀. Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.
Ifi 21:22-27 Yoruba Bible (YCE)
N kò rí Tẹmpili ninu ìlú náà. Nítorí Oluwa Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ni Tẹmpili ibẹ̀. Ìlú náà kò nílò ìmọ́lẹ̀ oòrùn tabi ti òṣùpá, nítorí pé ògo Ọlọrun ni ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí i; Ọ̀dọ́ Aguntan ni àtùpà ibẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa rìn ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọba ilé-ayé yóo mú ọlá wọn wá sinu rẹ̀. Wọn kò ní ti àwọn ìlẹ̀kùn ìlú náà ní gbogbo ọ̀sán; òru kò sì ní sí níbẹ̀. Wọn yóo mú ẹwà ati ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sí inú rẹ̀. Ohun ìdọ̀tí kan kò ní wọ inú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń ṣe ohun ẹ̀gbin tabi èké kò ní wọ ibẹ̀. Àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Aguntan nìkan ni yóo wọ ibẹ̀.
Ifi 21:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀: nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn. Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i: nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀: àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀. A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu ibodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀. Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀. Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn.