Ifi 21:10-22

Ifi 21:10-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si mu mi lọ ninu Ẹmí si òke nla kan ti o si ga, o si fi ilu nì hàn mi, Jerusalemu mimọ́, ti nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, Ti o ni ogo Ọlọrun: imọlẹ rẹ̀ si dabi okuta iyebiye gidigidi, ani bi okuta jasperi, o mọ́ bi kristali; O si ni odi nla ati giga, o si ni ẹnubode mejila, ati ni awọn ẹnubode na angẹli mejila ati orukọ ti a kọ sara wọn ti iṣe orukọ awọn ẹ̀ya mejila ti awọn ọmọ Israeli: Ni ìha ìla-õrùn ẹnubode mẹta; ni ìha ariwa ẹnubode mẹta; ni ìha gusù ẹnubode mẹta; ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹnubode mẹta. Odi ilu na si ni ipilẹ mejila, ati lori wọn orukọ awọn Aposteli mejila ti Ọdọ-Agutan. Ẹniti o si mba mi sọ̀rọ ni ifefe wura kan fun iwọn lati fi wọ̀n ilu na ati awọn ẹnubode rẹ̀, ati odi rẹ̀. Ilu na si lelẹ ni ibú mẹrin li ọgbọgba, gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ si dọgba: o si fi ifefe nì wọ̀n ilu na, o jẹ ẹgbata oṣuwọn furlongi: gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ ati gìga rẹ̀ si dọ́gba. O si wọ̀n odi rẹ̀, o jẹ ogoje igbọnwọ le mẹrin, gẹgẹ bi oṣuwọn enia, eyini ni, ti angẹli na. Ohun ti a sì fi mọ odi na ni jasperi: ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí ti o mọ́ kedere. A fi onirũru okuta iyebiye ṣe ipilẹ ogiri ilu na lọ́ṣọ. Ipilẹ ikini jẹ jasperi; ekeji, safiru; ẹkẹta, kalkedoni; ẹkẹrin, smaragdu: Ẹkarun, sardoniki; ẹkẹfa, sardiu; ekeje, krisoliti; ẹkẹjọ berili; ẹkẹsan, topasi; ẹkẹwa, krisoprasu; ẹkọkanla, hiakinti; ekejila, ametisti. Ẹnubode mejejila jẹ perli mejila: olukuluku ẹnubode jẹ perli kan; ọ̀na igboro ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí didán. Emi kò si ri tẹmpili ninu rẹ̀: nitoripe Oluwa Ọlọrun Olodumare ni tẹmpili rẹ̀, ati Ọdọ-Agutan.

Ifi 21:10-22 Yoruba Bible (YCE)

Ó bá gbé mi ninu ẹ̀mí lọ sí orí òkè ńlá kan tí ó ga, ó fi Jerusalẹmu ìlú mímọ́ náà hàn mí, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ògo Ọlọrun ń tàn lára rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye. Ẹwà rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye tí ó mọ́lẹ̀ gaara. Odi ìlú náà nípọn, ó sì ga. Ó ní ìlẹ̀kùn mejila, àwọn angẹli mejila wà níbi àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. A kọ àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli mejila sí ara àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. Ìlẹ̀kùn mẹta wà ní ìhà ìlà oòrùn, mẹta wà ní ìhà àríwá, mẹta wà ni ìhà gúsù, mẹta wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Odi ìlú náà ní ìpìlẹ̀ mejila. Orúkọ mejila ti àwọn aposteli mejila ti Ọ̀dọ́ Aguntan wà lára wọn. Ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá ìwọnlẹ̀ wúrà lọ́wọ́ láti fi wọn ìlú náà ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, ati odi rẹ̀. Igun mẹrẹẹrin ìlú náà dọ́gba, bákan náà ni gígùn rẹ̀ ati ìbú rẹ̀. Ó fi ọ̀pá ìwọnlẹ̀ náà wọn ìlú náà. Bákan náà ni gígùn rẹ̀, ati ìbú rẹ̀, ati gíga rẹ̀. Ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹjọ (1500) ibùsọ̀. Ó wá wọn odi rẹ̀, ó ga tó igba ẹsẹ̀ ó lé ogún (220) gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n eniyan tí angẹli náà ń lò. Òkúta iyebíye ni wọ́n fi mọ odi náà. Wúrà ni gbogbo ìlú náà tí ó mọ́ gaara bíi dígí. Òkúta iyebíye oríṣìíríṣìí ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ odi ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ kinni, òkúta iyebíye oríṣìí kan, ekeji oríṣìí mìíràn, ẹkẹta oríṣìí mìíràn, ẹkẹrin, bẹ́ẹ̀; ẹkarun-un, bẹ́ẹ̀; ẹkẹfa, bẹ́ẹ̀, ekeje bẹ́ẹ̀, ẹkẹjọ, bẹ́ẹ̀, ẹkẹsan-an, bẹ́ẹ̀, ẹkẹwaa, bẹ́ẹ̀, ikọkanla bẹ́ẹ̀, ekejila náà, bẹ́ẹ̀. Òkúta tí ó dàbí ìlẹ̀kẹ̀ ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn mejeejila ìlú náà; ẹyọ òkúta kọ̀ọ̀kan ni wọ́n fi gbẹ́ ìlẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan. Wúrà ni wọ́n yọ́ sí títì ìlú náà. Ó mọ́ gaara bíi dígí. N kò rí Tẹmpili ninu ìlú náà. Nítorí Oluwa Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ni Tẹmpili ibẹ̀.

Ifi 21:10-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fi ìlú náà hàn mi, Jerusalẹmu mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Tí ó ní ògo Ọlọ́run: ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasperi, ó mọ́ bí Kirisitali; Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu ibodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu ibodè náà angẹli méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Israẹli; Ní ìhà ìlà-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà gúúsù ẹnu ibodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta. Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Aposteli méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn. Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu ibodè rẹ̀, àti odi rẹ̀. Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba: ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàafà ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba. Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ́ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí angẹli náà. A sì fi jasperi mọ odi ìlú náà. Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere. A fi onírúurú òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ èkínní jẹ́ jasperi; èkejì, safiru; ẹ̀kẹta, kalkedoni ẹ̀kẹrin, emeradi, ẹ̀karùnún, sardoniki; ẹ̀kẹfà, kaneliani; èkeje, krisoliti; ẹ̀kẹjọ, bereli; ẹ̀kẹsànán, topasi; ẹ̀kẹwàá, krisoprasu; ẹ̀kọkànlá, jakiniti; èkejìlá, ametisiti. Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ pearli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán. Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀: nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn.