Ifi 21:1-4
Ifi 21:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
MO si ri ọrun titun kan ati aiye titun kan: nitoripe ọrun ti iṣaju ati aiye iṣaju ti kọja lọ; okun kò si si mọ́. Mo si ri ilu mimọ́ nì, Jerusalemu titun nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, ti a mura silẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọ́ fun ọkọ rẹ̀. Mo si gbọ́ ohùn nla kan lati ori itẹ́ nì wá, nwipe, Kiyesi i, agọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mã ba wọn gbé, nwọn o si mã jẹ enia rẹ̀, ati Ọlọrun tikararẹ̀ yio wà pẹlu wọn, yio si mã jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn; kì yio si si ikú mọ́, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹ̃ni ki yio si irora mọ́: nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ.
Ifi 21:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Mo rí ọ̀run titun ati ayé titun, ayé ti àkọ́kọ́ ti kọjá lọ. Òkun kò sì sí mọ́. Lẹ́yìn náà mo rí ìlú mímọ́ náà, Jerusalẹmu titun, tí ó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sọ̀kalẹ̀ láti òkè wá. A ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ bí ìgbà tí a bá ṣe iyawo lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn; yóo nu gbogbo omijé nù ní ojú wọn. Kò ní sí ikú mọ́, tabi ọ̀fọ̀ tabi ẹkún tabi ìrora. Nítorí àwọn ohun ti àtijọ́ ti kọjá lọ.”
Ifi 21:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan: nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; Òkun kò sì ṣí mọ́. Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerusalẹmu tuntun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.”