Ifi 20:1-3
Ifi 20:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
MO si ri angẹli kan nti ọrun sọkalẹ wá, ti on ti ìṣika ọgbun nì, ati ẹ̀wọn nla kan li ọwọ́ rẹ̀. O si di dragoni na mu, ejò atijọ nì, ti iṣe Èṣu, ati Satani, o si dè e li ẹgbẹ̀run ọdún. O si gbé e sọ sinu ọgbun na, o si ti i, o si fi èdidi di i lori rẹ̀, ki o má bã tan awọn orilẹ-ède jẹ mọ́ titi ẹgbẹrun ọdún na yio fi pé: lẹhin eyi, a kò le ṣai tu u silẹ fun igba diẹ.
Ifi 20:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Mo wá rí angẹli kan tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó mú kọ́kọ́rọ́ kànga tí ó jìn pupọ náà lọ́wọ́ ati ẹ̀wọ̀n gígùn. Ó bá ki Ẹranko Ewèlè náà mọ́lẹ̀, ejò àtijọ́ náà tíí ṣe Èṣù tabi Satani, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é fún ẹgbẹrun ọdún. Ó bá jù ú sinu kànga tí ó jìn pupọ náà, ó pa ìdérí rẹ̀ dé mọ́ ọn lórí. Ó bá fi èdìdì dì í kí ó má baà tan àwọn eniyan jẹ mọ́ títí ẹgbẹrun ọdún yóo fi parí. Lẹ́yìn náà, a óo dá a sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.
Ifi 20:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo sì rí angẹli kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun, àti ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. O sì di Dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbun náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé: Lẹ́yìn èyí, a kò le ṣàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.