Ifi 2:2-5
Ifi 2:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati lãlã rẹ, ati ìfarada rẹ, ati bi ara rẹ kò ti gba awọn ẹni buburu: ati bi iwọ si ti dan awọn ti npè ara wọn ni aposteli, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃ wo, ti iwọ si ri pe eleke ni wọn; Ti iwọ si farada ìya, ati nitori orukọ mi ti o si fi aiya rán, ti ãrẹ̀ kò si mu ọ. Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, pe, iwọ ti fi ifẹ rẹ iṣaju silẹ. Nitorina ranti ibiti iwọ gbé ti ṣubu, ki o si ronupiwada, ki o si ṣe iṣẹ iṣaju; bi kò si ṣe bẹ̃, emi ó si tọ̀ ọ wá, emi o si ṣí ọpá fitila rẹ kuro ni ipò rẹ̀, bikoṣe bi iwọ ba ronupiwada.
Ifi 2:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n. O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ. Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O ti kọ ìfẹ́ tí o ní nígbà tí o kọ́kọ́ gbàgbọ́ sílẹ̀. Nítorí náà, ranti bí o ti ga tó tẹ́lẹ̀ kí o tó ṣubú; ronupiwada, kí o sì ṣiṣẹ́ bíi ti àkọ́kọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, bí o kò bá ronupiwada, n óo mú ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní ipò rẹ̀.
Ifi 2:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú: àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọ́n kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n; Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ. Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀. Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà.