Ifi 19:11-21

Ifi 19:11-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

Mo si ri ọrun ṣí silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun. Oju rẹ̀ dabi ọwọ iná, ati li ori rẹ̀ ni ade pupọ̀ wà; o si ni orukọ kan ti a kọ, ti ẹnikẹni kò mọ̀, bikoṣe on tikararẹ̀. A si wọ̀ ọ li aṣọ ti a tẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ: a si npè orukọ rẹ̀ ni Ọ̀rọ Ọlọrun. Awọn ogun ti mbẹ li ọrun ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, funfun ati mimọ́, si ntọ ọ lẹhin lori ẹṣin funfun. Ati lati ẹnu rẹ̀ ni idà mimu ti njade lọ, ki o le mã fi ṣá awọn orilẹ-ède: on o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn: o si ntẹ ifúnti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare. O si ni lara aṣọ rẹ̀ ati ni itan rẹ̀ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA. Mo si ri angẹli kan duro ninu õrùn; o si fi ohùn rara kigbe, o nwi fun gbogbo awọn ẹiyẹ ti nfò li agbedemeji ọrun pe, Ẹ wá, ẹ si kó ara nyin jọ pọ̀ si àse-alẹ nla Ọlọrun; Ki ẹnyin ki o le jẹ ẹran-ara awọn ọba, ati ẹran-ara awọn olori ogun, ati ẹran-ara awọn enia alagbara, ati ẹran awọn ẹṣin, ati ti awọn ti o joko lori wọn, ati ẹran-ara enia gbogbo, ati ti omnira, ati ti ẹrú, ati ti ewe ati ti àgba. Mo si ri ẹranko na ati awọn ọba aiye, ati awọn ogun wọn ti a gbájọ lati ba ẹniti o joko lori ẹṣin na ati ogun rẹ̀ jagun. A si mu ẹranko na, ati woli eke nì pẹlu rẹ̀, ti o ti nṣe iṣẹ iyanu niwaju rẹ̀, eyiti o ti fi ntàn awọn ti o gbà àmi ẹranko na ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀ jẹ. Awọn mejeji yi li a sọ lãye sinu adagun iná ti nfi sulfuru jò. Awọn iyokù li a si fi idà ẹniti o joko lori ẹṣin na pa, ani idà ti o ti ẹnu rẹ̀ jade: gbogbo awọn ẹiyẹ si ti ipa ẹran-ara wọn yó.

Ifi 19:11-21 Yoruba Bible (YCE)

Mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀. Mo wá rí ẹṣin funfun kan. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Olódodo ati Olóòótọ́, nítorí pẹlu òdodo ni ó ń ṣe ìdájọ́, tí ó sì ń jagun. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná. Ó dé adé pupọ tí a kọ orúkọ sí, orúkọ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ àfi òun alára. Ó wọ ẹ̀wù tí a rẹ sinu ẹ̀jẹ̀. Orúkọ tí à ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ogun ọ̀run ń tẹ̀lé e, wọ́n gun ẹṣin funfun. Aṣọ tí wọ́n wọ̀ funfun, ó sì mọ́. Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare. A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.” Mo tún rí angẹli kan tí ó dúró ninu oòrùn, ó kígbe sí àwọn ẹyẹ tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run pé, “Ẹ wá péjọ sí ibi àsè ńlá Ọlọrun, kí ẹ lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba ati ti àwọn ọ̀gágun, ati ti àwọn alágbára, ati ẹran ẹṣin ati ti àwọn tí wọ́n gùn wọ́n, ati ẹran-ara àwọn òmìnira ati ti ẹrú, ti àwọn mẹ̀kúnnù ati ti àwọn ọlọ́lá.” Mo wá rí ẹranko náà ati àwọn ọba ilé ayé ati àwọn ọmọ-ogun wọn. Wọ́n péjọ láti bá ẹni tí ó gun ẹṣin funfun náà ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jagun. A mú ẹranko náà lẹ́rú, pẹlu wolii èké tí ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì níwájú rẹ̀, tí ó ti tan àwọn tí wọ́n gba àmì ẹranko náà jẹ, ati àwọn tí wọ́n júbà ère rẹ̀. A wá gbé àwọn mejeeji láàyè, a sọ wọ́n sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá. Wọ́n fi idà tí ó wà lẹ́nu ẹni tí ó gun ẹṣin funfun pa àwọn yòókù. Gbogbo àwọn ẹyẹ bá ń jẹ ẹran-ara wọn ní àjẹrankùn.

Ifi 19:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ: ọba àwọn ọba àti olúwa àwọn olúwa. Mo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run; kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.” Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun. A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba ààmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó. Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde: Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.