Ifi 18:4-24

Ifi 18:4-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

Mo si gbọ́ ohùn miran lati ọrun wá, nwipe, Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹnyin enia mi, ki ẹ má bã ṣe alabapin ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ki ẹ má bã si ṣe gbà ninu iyọnu rẹ̀. Nitori awọn ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gá ani de ọrun, Ọlọrun si ti ranti aiṣedẽdẽ rẹ̀. San a fun u, ani bi on ti san fun-ni, ki o si ṣe e ni ilọpo meji fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: ninu ago na ti o ti kùn, on ni ki ẹ si kún fun u ni meji. Niwọn bi o ti yin ara rẹ̀ logo to, ti o si huwa wọbia, niwọn bẹ̃ ni ki ẹ da a loro ki ẹ si fún u ni ibanujẹ: nitoriti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, mo joko bi ọbabirin, emi kì si iṣe opó, emi ki yio si ri ibinujẹ lai. Nitorina ni ijọ kan ni iyọnu rẹ̀ yio de, ikú, ati ibinujẹ, ati ìyan; a o si fi iná sun u patapata: nitoripe alagbara ni Oluwa Ọlọrun ti nṣe idajọ rẹ̀. Ati awọn ọba aiye, ti o ti mba a ṣe àgbere, ti nwọn si mba a hu iwà wọbia, yio si pohùnrere ẹkún le e lori, nigbati nwọn ba wo ẹ̃fin ijona rẹ̀. Nwọn o duro li okere rére nitori ibẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, Babiloni, ilu alagbara ni! nitori ni wakati kan ni idajọ rẹ de. Awọn oniṣowo aiye si nsọkun, nwọn si nṣọ̀fọ lori rẹ̀; nitoripe ẹnikẹni kò rà ọjà wọn mọ́: Ọjà wura, ati ti fadaka, ati ti okuta iyebiye, ati ti perli, ati ti aṣọ ọgbọ wíwe, ati ti elese aluko, ati ti ṣẹ́dà, ati ti ododó, ati ti gbogbo igi olõrun didun, ati ti olukuluku ohun èlo ti ehin-erin, ati ti olukuluku ohun èlo ti a fi igi iyebiye ṣe, ati ti idẹ, ati ti irin, ati ti okuta marbili, Ati ti kinamoni, ati ti oniruru ohun olõrun didun, ati ti ohun ikunra, ati ti turari, ati ti ọti-waini, ati ti oróro, ati ti iyẹfun daradara, ati ti alikama, ati ti ẹranlá, ati ti agutan, ati ti ẹṣin, ati ti kẹkẹ́, ati ti ẹrú, ati ti ọkàn enìa. Ati awọn eso ti ọkàn rẹ nṣe ifẹkufẹ si, sì lọ kuro lọdọ rẹ, ati ohun gbogbo ti o dùn ti o si dara ṣegbe mọ ọ loju, a kì yio si tún ri wọn mọ́ lai. Awọn oniṣowo nkan wọnyi, ti a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọrọ̀, yio duro li òkere rére nitori ìbẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã sọkun, nwọn o si mã ṣọ̀fọ, Wipe, Ègbé, egbé ni fun ilu nla nì, ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, ati ti elese aluko, ati ti ododó, ati ti a si fi wura ṣe lọṣọ́, pẹlu okuta iyebiye ati perli! Nitoripe ni wakati kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tobẹ̃ di asan. Ati olukuluku olori ọkọ̀, ati olukuluku ẹniti nrin oju omi lọ si ibikibi, ati awọn ti nṣiṣẹ, ninu ọkọ̀, ati awọn ti nṣowo oju okun duro li òkere rére, Nwọn si kigbe nigbati nwọn ri ẹ̃fin jijona rẹ̀, wipe, Ilu wo li o dabi ilu nla yi? Nwọn si kù ekuru si ori wọn, nwọn kigbe, nwọn sọkun, nwọn si nṣọfọ, wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, ninu eyi ti a sọ gbogbo awọn ti o ni ọkọ̀ li okun di ọlọrọ̀ nipa ohun iyebiye rẹ̀! nitoripe ni wakati kan a sọ ọ di ahoro. Yọ̀ lori rẹ̀, iwọ ọrun, ati ẹnyin aposteli mimọ́ ati woli; nitori Ọlọrun ti gbẹsan nyin lara rẹ̀. Angẹli alagbara kan si gbé okuta kan soke, o dabi ọlọ nla, o si jù u sinu okun, wipe, Bayi li a o fi agbara nla bì Babiloni ilu nla nì wó, a kì yio si ri i mọ́ lai. Ati ohùn awọn aludùru, ati ti awọn olorin, ati ti awọn afunfère, ati ti awọn afunpè ni a kì yio si gbọ́ ninu rẹ mọ́ rara; ati olukuluku oniṣọnà ohunkohun ni a kì yio si ri ninu rẹ mọ́ lai; ati iró ọlọ li a kì yio si gbọ́ mọ́ ninu rẹ lai; Ati imọlẹ fitila ni kì yio si tàn ninu rẹ mọ́ lai; a ki yio si gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́ lai: nitoripe awọn oniṣowo rẹ li awọn ẹni nla aiye; nitoripe nipa oṣó rẹ li a fi tàn orilẹ-ède gbogbo jẹ. Ati ninu rẹ̀ li a gbé ri ẹ̀jẹ awọn woli, ati ti awọn enia mimọ́, ati ti gbogbo awọn ti a pa lori ilẹ aiye.

Ifi 18:4-24 Yoruba Bible (YCE)

Mo tún gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run tí ó sọ pé, “Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi, kí ẹ má baà ní ìpín ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ má baà fara gbá ninu ìjìyà rẹ̀. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run, Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀. Ṣe fún un bí òun náà ti ṣe fún eniyan. Gbẹ̀san lára rẹ̀ ní ìlọ́po meji ìwà rẹ̀. Ife tí ó fi ń bu ọtí fún eniyan ni kí o fi bu ọtí tí ó le ní ìlọ́po meji fún òun alára. Bí ó ti ṣe ń jẹ ọlá, tí ó ń jẹ ayé tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí o fún un ní ìrora ati ìbànújẹ́. Ó ń sọ ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọba orí ìtẹ́ ni mí, èmi kì í ṣe opó, ojú mi kò ní rí ìbànújẹ́.’ Nítorí èyí, ní ọjọ́ kan náà ni oríṣìíríṣìí òfò yóo dé bá a, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ati ọ̀fọ̀, ati ìyàn. Iná yóo tún jó o ní àjórun, nítorí alágbára ni Oluwa Ọlọrun tí ó ti ń ṣe ìdájọ́ fún un.” Àwọn ọba ayé ati àwọn tí wọ́n ti bá a ṣe àgbèrè, tí wọ́n ti ń bá a jayé yóo sunkún, wọn óo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí nígbà tí wọ́n bá rí èéfín iná tí ń jó o. Wọn óo dúró ní òkèèrè nítorí ẹ̀rù tí yóo máa bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀. Wọn óo sọ pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ọ! Ìlú ńlá, Babiloni ìlú alágbára! Nítorí ní wakati kan ni ìparun dé bá ọ.” Àwọn oníṣòwò ayé yóo sunkún, wọn yóo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí, nítorí wọn kò rí ẹni ra ọjà wọn mọ́; àwọn nǹkan bíi: Wúrà, fadaka, òkúta iyebíye, oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀, aṣọ funfun ati àlàárì, ati sányán ati aṣọ pupa; oríṣìíríṣìí pákó, ati àwọn ohun èèlò tí a fi eyín erin, igi iyebíye, idẹ, irin, ati òkúta ṣe; oríṣìíríṣìí òróró ìkunra, turari ati òjíá, ọtí, òróró olifi, ọkà, ati àgbàdo, ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun, ẹrú, àní ẹ̀mí eniyan. Wọ́n ní, “Èso tí o fẹ́ràn kò sí mọ́, gbogbo ìgbé-ayé fàájì ati ti ìdẹ̀ra ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ, o kò tún ní rí irú rẹ̀ mọ́.” Àwọn oníṣòwò wọnyi, tí wọ́n ti di olówó ninu rẹ̀ yóo dúró ní òkèèrè nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀, wọn óo máa sunkún, wọn óo máa ṣọ̀fọ̀. Wọn óo máa wí pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà! Ìlú tí ó wọ aṣọ funfun, ati aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa. Ìlú tí wúrà pọ̀ níbẹ̀ ati òkúta iyebíye ati ìlẹ̀kẹ̀! Ní wakati kan péré ni gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ run!” Nígbà náà ni gbogbo ọ̀gá àwọn awakọ̀ ojú omi, ati gbogbo àwọn tí ó ń wọ ọkọ̀ ati àwọn atukọ̀ ati àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ ojú omi òkun lọ dúró ní òkèèrè. Wọ́n ń kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí èéfín iná tí ń jó ìlú náà. Wọ́n wá ń sọ pé, “Ìlú wo ni ó dàbí ìlú ńlá yìí?” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sórí ara wọn, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń ṣọ̀fọ̀. Wọ́n ní, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà, níbi tí gbogbo àwọn tí wọn ní ọkọ̀ lójú òkun ti di ọlọ́rọ̀ nípa ọrọ̀ rẹ̀, nítorí ní wakati kan ó ti di ahoro! Ọ̀run, yọ̀ lórí rẹ̀! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin eniyan Ọlọrun, ẹ̀yin aposteli, ati ẹ̀yin wolii, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìdájọ́ fún un bí òun náà ti ṣe fún yín!” Ọ̀kan ninu àwọn angẹli alágbára bá gbé òkúta tí ó tóbi bí ọlọ ògì, ó jù ú sinu òkun, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni a óo fi tagbára-tagbára sọ Babiloni ìlú ńlá náà mọ́lẹ̀ tí a kò ní rí i mọ́. A kò tún ní gbọ́ ohùn fèrè ati ti àwọn olórin tabi ti ohùn ìlù ati ti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ninu rẹ mọ́. A kò ní tún rí àwọn oníṣọ̀nà fún iṣẹ́ ọnà kan ninu rẹ mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ ninu rẹ mọ́. Iná àtùpà kan kò ní tàn ninu rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́. Nígbà kan rí àwọn oníṣòwò rẹ ni àwọn gbajúmọ̀ ninu ayé. O fi ìwà àjẹ́ tan gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ.” Ninu rẹ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wolii ati ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun, ati gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n pa lórí ilẹ̀ ayé.

Ifi 18:4-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé: “ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’ kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀. San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní, kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì. Níwọ́n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó, tí ó sì hùwà wọ̀bìà, níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́; nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’ Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé, ikú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn; a ó sì fi iná sun ún pátápátá: nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. “Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbèrè, tiwọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀. Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, Babeli ìlú alágbára nì! Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’ “Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́: Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti Pearli, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti ṣẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabu. Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn. “Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé. Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali! Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’ “Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré, wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’ Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀! Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’ “Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì! Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀ nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.” Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé: “Báyìí ní a ó fi agbára ńlá bí i Babeli ìlú ńlá ni wó, a kì yóò sì rí i mọ́ láé. Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin, àti ti àwọn afunfèrè, àti ti àwọn afùnpè, ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara; àti olúkúlùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé: Àti ìró ọlọ ní a kì yóò sì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé; Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé; a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé: nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé; nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀-èdè gbogbo jẹ. Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì, àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”