Ifi 1:17-18
Ifi 1:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati mo ri i, mo wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ bi ẹniti o kú. O si fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ le mi, o nwi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru; Emi ni ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku.
Ifi 1:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó bá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi. Ó ní, “Má bẹ̀rù. Èmi ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn. Èmi ni ẹni tí ó wà láàyè. Mo kú, ṣugbọn mo ti jí, mo sì wà láàyè lae ati laelae. Àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú wà lọ́wọ́ mi.
Ifi 1:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.