O. Daf 91:1-4
O. Daf 91:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸNITI o joko ni ibi ìkọkọ Ọga-ogo ni yio ma gbe abẹ ojiji Olodumare. Emi o wi fun Ọlọrun pe, Iwọ li àbo ati odi mi; Ọlọrun mi, ẹniti emi gbẹkẹle. Nitõtọ on o gbà ọ ninu ikẹkun awọn pẹyẹpẹyẹ, ati ninu àjakalẹ-àrun buburu. Yio fi iyẹ́ rẹ̀ bò ọ, abẹ iyẹ́-apa rẹ̀ ni iwọ o si gbẹkẹle: otitọ rẹ̀ ni yio ṣe asà ati apata rẹ.
O. Daf 91:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ń gbé abẹ́ ààbò Ọ̀gá Ògo, tí ó wà lábẹ́ òjìji Olodumare, yóo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni ààbò ati odi mi, Ọlọrun mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé.” Nítorí yóo yọ ọ́ ninu okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ ati ninu àjàkálẹ̀ àrùn apanirun. Yóo da ìyẹ́ rẹ̀ bò ọ́, lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni o óo ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóo jẹ́ asà ati apata rẹ.
O. Daf 91:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè. Èmi yóò sọ nípa ti OLúWA pé, “Òun ni ààbò àti odi mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”. Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú. Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.