O. Daf 91:1-12
O. Daf 91:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸNITI o joko ni ibi ìkọkọ Ọga-ogo ni yio ma gbe abẹ ojiji Olodumare. Emi o wi fun Ọlọrun pe, Iwọ li àbo ati odi mi; Ọlọrun mi, ẹniti emi gbẹkẹle. Nitõtọ on o gbà ọ ninu ikẹkun awọn pẹyẹpẹyẹ, ati ninu àjakalẹ-àrun buburu. Yio fi iyẹ́ rẹ̀ bò ọ, abẹ iyẹ́-apa rẹ̀ ni iwọ o si gbẹkẹle: otitọ rẹ̀ ni yio ṣe asà ati apata rẹ. Iwọ kì yio bẹ̀ru nitori ẹ̀ru oru; tabi fun ọfa ti nfo li ọsán; Tabi fun àjakalẹ-àrun ti nrìn kiri li okunkun, tabi fun iparun ti nrun-ni li ọsángangan. Ẹgbẹrun yio ṣubu li ẹgbẹ rẹ, ati ẹgbarun li apa ọtún rẹ: ṣugbọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ. Kiki oju rẹ ni iwọ o ma fi ri, ti o si ma fi wo ère awọn enia buburu. Nitori iwọ, Oluwa, ni iṣe ãbo mi, iwọ ti fi Ọga-ogo ṣe ibugbe rẹ. Buburu kan kì yio ṣubu lu ọ, bẹ̃li arunkarun kì yio sunmọ ile rẹ. Nitori ti yio fi aṣẹ fun awọn angeli rẹ̀ nitori rẹ, lati pa ọ mọ́ li ọ̀na rẹ gbogbo. Nwọn o gbé ọ soke li ọwọ́ wọn, ki iwọ ki o má ba fi ẹṣẹ rẹ gbun okuta.
O. Daf 91:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ń gbé abẹ́ ààbò Ọ̀gá Ògo, tí ó wà lábẹ́ òjìji Olodumare, yóo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni ààbò ati odi mi, Ọlọrun mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé.” Nítorí yóo yọ ọ́ ninu okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ ati ninu àjàkálẹ̀ àrùn apanirun. Yóo da ìyẹ́ rẹ̀ bò ọ́, lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni o óo ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóo jẹ́ asà ati apata rẹ. O ò ní bẹ̀rù ìdágìrì òru, tabi ọfà tí ń fò kiri ní ọ̀sán, tabi àjàkálẹ̀ àrùn tí ń jà kiri ninu òkùnkùn, tabi ìparun tí ń ṣeni lófò ní ọ̀sán gangan. Ẹgbẹrun lè ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, tabi ẹgbaarun ni apá ọ̀tún rẹ; ṣugbọn kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ. Ojú nìkan ni óo kàn máa fi rí wọn, tí o óo sì máa fi wo èrè àwọn eniyan burúkú. Nítorí tí ìwọ ti fi OLUWA ṣe ààbò rẹ, o sì ti fi Ọ̀gá Ògo ṣe ibùgbé rẹ, ibi kankan kò ní dé bá ọ, bẹ́ẹ̀ ni àjálù kankan kò ní súnmọ́ ilé rẹ. Nítorí yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀, nítorí rẹ, pé kí wọ́n máa pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè, kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.
O. Daf 91:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè. Èmi yóò sọ nípa ti OLúWA pé, “Òun ni ààbò àti odi mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”. Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú. Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi. Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru, tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán, Tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn, tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan. Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, ẹgbàárùn-ún ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú. Nítorí ìwọ fi OLúWA ṣe ààbò rẹ, ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ. Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́ Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ. Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ; Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn, nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.