O. Daf 90:10-16
O. Daf 90:10-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Adọrin ọdun ni iye ọjọ ọdun wa; bi o si ṣepe nipa ti agbara, bi nwọn ba to ọgọrin ọdun, agbara wọn lãla on ibinujẹ ni; nitori pe a kì o pẹ ke e kuro, awa a si fò lọ. Tali o mọ̀ agbara ibinu rẹ? gẹgẹ bi ẹ̀ru rẹ, bẹ̃ni ibinu rẹ. Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n. Pada, Oluwa, yio ti pẹ to? yi ọkàn pada nitori awọn ọmọ-ọdọ rẹ. Fi ãnu rẹ tẹ́ wa li ọrùn ni kutukutu; ki awa ki o le ma yọ̀, ati ki inu wa ki o le ma dùn li ọjọ wa gbogbo. Mu inu wa dùn bi iye ọjọ ti iwọ pọ́n wa loju, ati iye ọdun ti awa ti nri buburu. Jẹ ki iṣẹ rẹ ki o hàn si awọn ọmọ-ọ̀dọ rẹ, ati ogo rẹ si awọn ọmọ wọn.
O. Daf 90:10-16 Yoruba Bible (YCE)
Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa; pẹlu ipá a lè tó ọgọrin; sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu; kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ. Ta ló mọ agbára ibinu rẹ? Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí? Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa, kí á lè kọ́gbọ́n. Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa? Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀, kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí o ti fi pọ́n wa lójú, ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi. Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ, kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn.
O. Daf 90:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá, bi ó sì ṣe pé nípa agbára tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún, agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni, nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò, àwa a sì fò lọ. Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ? Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ. Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára, kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n. Yípadà, OLúWA! Yóò ti pẹ́ tó? Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ. Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ, kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀ kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́. Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú, fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà. Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.