O. Daf 9:7-10
O. Daf 9:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Oluwa yio wà titi lailai: o ti tẹ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ fun idajọ. On o si ṣe idajọ aiye li ododo, yio ṣe idajọ fun awọn enia li otitọ ìwa. Oluwa ni yio ṣe àbo awọn ẹni-inilara, àbo ni igba ipọnju. Awọn ti o si mọ̀ orukọ rẹ o gbẹkẹ le ọ: nitori iwọ, Oluwa, kò ti ikọ̀ awọn ti nṣe afẹri rẹ silẹ.
O. Daf 9:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae, ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé, yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú. Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ; nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀.
O. Daf 9:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA jẹ ọba títí láé; ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo; yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo. OLúWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú. Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ, nítorí, OLúWA, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.