O. Daf 9:13-20
O. Daf 9:13-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣãnu fun mi, Oluwa; rò iṣẹ́ ti emi nṣẹ́ lọwọ awọn ti o korira mi, iwọ ti o gbé ori mi soke kuro li ẹnu-ọ̀na ikú. Ki emi ki o le ma fi gbogbo iyìn rẹ hàn li ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin Sioni, emi o ma yọ̀ ni igbala rẹ. Awọn orilẹ-ède jìn sinu ọ̀fin ti nwọn wà: ninu àwọn ti nwọn dẹ silẹ li ẹsẹ ara wọn kọ́. A mọ̀ Oluwa, nipa idajọ ti o nṣe: nipa iṣẹ ọwọ enia buburu li a fi ndẹkùn mu u. Ori awọn enia buburu li a o dà si ọrun apadi, ati gbogbo orilẹ-ède ti o gbagbe Ọlọrun. Nitori pe a kì yio gbagbe awọn alaini lailai: abá awọn talaka kì yio ṣegbe lailai. Oluwa, dide; máṣe jẹ ki enia ki o bori: jẹ ki a ṣe idajọ awọn orilẹ-ède niwaju rẹ. Dẹru ba wọn, Oluwa: ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ ara wọn pe, enia ṣa ni nwọn.
O. Daf 9:13-20 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ṣàánú fún mi! Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú. Gbà mí kúrò létí bèbè ikú, kí n lè kọrin ìyìn rẹ, kí n sì lè yọ ayọ̀ ìgbàlà rẹ lẹ́nu ibodè Sioni. Àwọn orílẹ̀-èdè ti jìn sinu kòtò tí wọ́n gbẹ́, wọ́n sì ti kó sinu àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀. OLUWA ti fi ara rẹ̀ hàn, ó ti ṣe ìdájọ́, àwọn eniyan burúkú sì ti kó sinu tàkúté ara wọn. Àwọn eniyan burúkú, àní, gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọrun, ni yóo lọ sinu isà òkú. Nítorí pé OLUWA kò ní fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn aláìní, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn talaka kò ní já sí òfo títí lae. Dìde, OLUWA, má jẹ́ kí eniyan ó borí, jẹ́ kí á ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ. OLUWA, da ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bò wọ́n, jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé aláìlágbára eniyan ni àwọn.
O. Daf 9:13-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú, Kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ. Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́; ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́. A mọ OLúWA nípa òdodo rẹ̀; àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé, ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé. Dìde, OLúWA, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí; Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ. Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, OLúWA; jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.