O. Daf 87:1-7
O. Daf 87:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
IPILẸ rẹ̀ mbẹ lori òke mimọ́ wọnni. Oluwa fẹ ẹnu-ọ̀na Sioni jù gbogbo ibujoko Jakobu lọ. Ohun ogo li a nsọ niti rẹ? Ilu Ọlọrun! Emi o da orukọ Rahabu ati Babeli lãrin awọn ti o mọ̀ mi: kiyesi Filistia ati Tire, pẹlu Etiopia: a bi eleyi nibẹ. Ati ni Sioni li a o wipe: ọkunrin yi ati ọkunrin nì li a bi ninu rẹ̀: ati Ọga-ogo tikararẹ̀ ni yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ. Oluwa yio kà, nigbati o ba nkọ orukọ awọn enia, pe, a bi eleyi nibẹ. Ati awọn olorin ati awọn ti nlu ohun-elo orin yio wipe: Gbogbo orisun mi mbẹ ninu rẹ.
O. Daf 87:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ní orí òkè mímọ́ ni ìlú tí OLUWA tẹ̀dó wà. OLUWA fẹ́ràn ẹnubodè Sioni ju gbogbo ìlú yòókù lọ ní ilẹ̀ Jakọbu. Ọpọlọpọ nǹkan tó lógo ni a sọ nípa rẹ, ìwọ ìlú Ọlọrun. Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi, n óo dárúkọ Ijipti ati Babiloni, Filistia ati Tire, ati Etiopia. Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.” A óo wí nípa Sioni pé, “Ibẹ̀ ni a ti bí eléyìí ati onítọ̀hún,” nítorí pé Ọ̀gá Ògo yóo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. OLUWA yóo ṣírò rẹ̀ mọ́ wọn nígbà tí ó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ní Sioni ni a ti bí eléyìí.” Àwọn akọrin ati àwọn afunfèrè ati àwọn tí ń jó yóo máa sọ pé, “Ìwọ, Sioni, ni orísun gbogbo ire wa.”
O. Daf 87:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́; OLúWA fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ. Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀, ìlú Ọlọ́run; “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ” Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ, “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.” OLúWA yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Sioni.” Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu ohun èlò orin yóò wí pé, “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”