O. Daf 84:5-7
O. Daf 84:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibukún ni fun enia na, ipá ẹniti o wà ninu rẹ: li ọkàn ẹniti ọ̀na rẹ wà. Awọn ti nla afonifoji omije lọ, nwọn sọ ọ di kanga; akọrọ-òjo si fi ibukún bò o. Nwọn nlọ lati ipá de ipá, ni Sioni ni awọn yọ niwaju Ọlọrun.
Pín
Kà O. Daf 84O. Daf 84:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn, tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún. Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ, wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi; àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀. Wọn ó máa ní agbára kún agbára, títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni.
Pín
Kà O. Daf 84O. Daf 84:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò. Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ wọn sọ ọ́ di kànga àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó; Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.
Pín
Kà O. Daf 84