O. Daf 8:1-9
O. Daf 8:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye! iwọ ti o gbé ogo rẹ kà ori awọn ọrun. Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ ati ọmọ-ọmu ni iwọ ti ṣe ilana agbara, nitori awọn ọta rẹ, nitori ki iwọ ki o le mu ọta olugbẹsan nì dakẹjẹ. Nigbati mo rò ọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ. Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rẹ̀? ati ọmọ enia, ti iwọ fi mbẹ̀ ẹ wò. Iwọ sa da a li onirẹlẹ diẹ jù Ọlọrun lọ, iwọ si ti fi ogo ati ọlá de e li ade. Iwọ mu u jọba iṣẹ ọwọ rẹ; iwọ si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀; Awọn agutan ati awọn malu pẹlu, ati awọn ẹranko igbẹ; Awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹja okun, ti o nkọja lọ nipa ọ̀na okun. Oluwa, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye!
O. Daf 8:1-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, Oluwa wa, orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé! Ìwọ ni o gbé ògo rẹ kalẹ̀ lókè ọ̀run. Àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ń kọrin ògo rẹ, wọ́n ti fi ìdí agbára rẹ múlẹ̀, nítorí àwọn tí ó kórìíra rẹ, kí á lè pa àwọn ọ̀tá ati olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́. Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀– Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀? Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀? O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun, o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé. O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀: àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó; àwọn ẹyẹ ojú ọrun, àwọn ẹja inú òkun, ati gbogbo nǹkan tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ ninu òkun. OLUWA, Oluwa wa, orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!
O. Daf 8:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, Olúwa wa, orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé! Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga ju àwọn ọ̀run lọ. Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ, láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́. Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ, iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti ìràwọ̀, tí ìwọ tí gbé kalẹ̀, kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀, àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀? Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ, ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá. Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ; ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀: àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù, àti ẹranko igbó, ẹyẹ ojú ọrun, àti ẹja inú Òkun, àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun. OLúWA, Olúwa wa, Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!