O. Daf 78:4-6
O. Daf 78:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awa kì yio pa wọn mọ́ kuro lọdọ awọn ọmọ wọn, ni fifi iyìn Oluwa, ati ipa rẹ̀, ati iṣẹ iyanu ti o ti ṣe hàn fun iran ti mbọ. Nitori ti o gbé ẹri kalẹ ni Jakobu, o si sọ ofin kan ni Israeli, ti o ti pa li aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki nwọn ki o le sọ wọn di mimọ̀ fun awọn ọmọ wọn. Ki awọn iran ti mbọ̀ ki o le mọ̀, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn
O. Daf 78:4-6 Yoruba Bible (YCE)
A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn; a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn– iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe. Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu; ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa, pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn. Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n, àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí, kí àwọn náà ní ìgbà tiwọn lè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn.
O. Daf 78:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífi ìyìn OLúWA, àti ipa rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn