O. Daf 78:29-32
O. Daf 78:29-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni nwọn jẹ, nwọn si yo jọjọ: nitoriti o fi ifẹ wọn fun wọn. Nwọn kò kuro ninu ifẹkufẹ wọn; nigbati onjẹ wọn si wà li ẹnu wọn. Ibinu Ọlọrun de si ori wọn, o pa awọn ti o sanra ninu wọn, o si lù awọn ọdọmọkunrin Israeli bolẹ. Ninu gbogbo wọnyi nwọn nṣẹ̀ siwaju, nwọn kò si gbà iṣẹ iyanu rẹ̀ gbọ́.
O. Daf 78:29-32 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn eniyan náà jẹ, wọ́n sì yó; nítorí pé Ọlọrun fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́. Ṣugbọn kí wọn tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, àní, nígbà tí wọn ṣì ń jẹun lọ́wọ́. Ọlọrun bínú sí wọn; ó pa àwọn tí ó lágbára jùlọ ninu wọn, ó sì lu àṣàyàn àwọn ọdọmọkunrin Israẹli pa. Sibẹsibẹ wọ́n tún dẹ́ṣẹ̀; pẹlu gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọn kò gbàgbọ́.
O. Daf 78:29-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún, nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn, Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn, ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀. Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú; nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́