O. Daf 78:13-16
O. Daf 78:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
O pin okun ni ìya, o si mu wọn là a ja; o si mu omi duro bi bèbe. Li ọsan pẹlu o fi awọsanma ṣe amọna wọn, ati li oru gbogbo pẹlu imọlẹ iná. O sán apata li aginju, o si fun wọn li omi mímu lọpọlọpọ bi ẹnipe lati inu ibú wá. O si mu iṣàn-omi jade wá lati inu apata, o si mu omi ṣàn silẹ bi odò nla.
O. Daf 78:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Ó pín òkun níyà, ó jẹ́ kí wọ́n kọjá láàrin rẹ̀; ó sì mú kí omi nàró bí òpó ńlá. Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán, ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru. Ó la àpáta ni aṣálẹ̀, ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú. Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta; ó sì mú kí ó ṣàn bí odò.
O. Daf 78:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga. Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná. Ó sán àpáta ní aginjù ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ẹni pé láti inú ibú wá. Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.