O. Daf 74:1-23
O. Daf 74:1-23 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ta wá nù títí ayé? Kí ló dé tí inú rẹ fi ń ru sí àwa aguntan pápá rẹ? Ranti ìjọ eniyan rẹ tí o ti rà ní ìgbà àtijọ́, àwọn ẹ̀yà tí o rà pada láti fi ṣe ogún tìrẹ; ranti òkè Sioni níbi tí o ti ń gbé rí. Rìn káàkiri kí o wo bí gbogbo ilẹ̀ ti di ahoro, wo bí ọ̀tá ti ba gbogbo nǹkan jẹ́ ninu ibi mímọ́ rẹ. Àwọn ọ̀tá rẹ bú ramúramù ninu ilé ìsìn rẹ; wọ́n ta àsíá wọn gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣẹ́gun. Wọ́n dàbí ẹni tí ó gbé àáké sókè, tí ó fi gé igi ìṣẹ́pẹ́. Gbogbo pákó tí a fi dárà sí ara ògiri ni wọ́n fi àáké ati òòlù fọ́. Wọ́n jó ibi mímọ́ rẹ kanlẹ̀; wọ́n sì ba ilé tí a ti ń pe orúkọ rẹ jẹ́. Wọ́n pinnu lọ́kàn wọn pé, “A óo bá wọn kanlẹ̀ patapata.” Wọ́n dáná sun gbogbo ilé ìsìn Ọlọrun tí ó wà ní ilẹ̀ náà. A kò rí àsíá wa mọ́, kò sí wolii mọ́; kò sì sí ẹnìkan ninu wa tí ó mọ bí ìṣòro wa yóo ti pẹ́ tó. Yóo ti pẹ́ tó, Ọlọrun, tí ọ̀tá yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀fẹ̀? Ṣé títí ayé ni ọ̀tá yóo máa gan orúkọ rẹ ni? Kí ló dé tí o ò ṣe nǹkankan? Kí ló dé tí o káwọ́ gbera? Ọlọrun, ìwọ ṣá ni ọba wa láti ìbẹ̀rẹ̀ wá; ìwọ ni o máa ń gbà wá là láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè. Ìwọ ni o fi agbára rẹ pín òkun níyà; o fọ́ orí àwọn ẹranko ńlá inú omi. Ìwọ ni o fọ́ orí Lefiatani túútúú; o sì fi òkú rẹ̀ ṣe ìjẹ fún àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀. Ìwọ ni o fọ́ àpáta tí omi tú jáde, tí odò sì ń ṣàn, ìwọ ni o sọ odò tí ń ṣàn di ilẹ̀ gbígbẹ. Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ náà sì ni òru, ìwọ ni o gbé òṣùpá ati oòrùn ró. Ìwọ ni o pa gbogbo ààlà ilẹ̀ ayé; ìwọ ni o dá ìgbà òjò ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. OLUWA, ranti pé àwọn ọ̀tá ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́; àwọn òmùgọ̀ eniyan sì ń fi orúkọ rẹ ṣe ẹlẹ́yà. Má fi ẹ̀mí àwa àdàbà rẹ lé àwọn ẹranko lọ́wọ́; má sì gbàgbé àwa eniyan rẹ tí ìyà ń jẹ títí lae. Ranti majẹmu rẹ; nítorí pé gbogbo kọ̀rọ̀ ilẹ̀ wa kún fún ìwà ipá. Má jẹ́ kí ojú ti àwọn tí à ń pọ́n lójú; jẹ́ kí àwọn tí ìyà ń jẹ ati àwọn aláìní máa yin orúkọ rẹ. Dìde Ọlọrun, gbèjà ara rẹ; ranti bí àwọn òmùgọ̀ eniyan tí ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru. Má gbàgbé ariwo àwọn ọ̀tá rẹ; àní, igbe àwọn tí ó gbógun tì ọ́, tí wọn ń ké láìdá ẹnu dúró.
O. Daf 74:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé? Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ? Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́, ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé. Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn, gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́. Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù láàrín ènìyàn rẹ, wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún ààmì; Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè láti gé igi igbó dídí. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín, ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà. Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀ wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́ Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!” Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà. A kò fún wa ní ààmì iṣẹ́ ìyanu kankan; kò sí wòlíì kankan ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà. Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run? Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé? Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ? Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n! Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́; Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé. Ìwọ ni ó la Òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ; Ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú; ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀. Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi; Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú; ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá. Ìwọ pààlà etí ayé; Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù. Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, OLúWA bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́. Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú; Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé. Bojú wo májẹ̀mú rẹ, nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà. Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ. Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò; rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́. Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ, bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.
O. Daf 74:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, ẽṣe ti iwọ fi ta wa nù titi lai! ẽṣe ti ibinu rẹ fi nrú si agutan papa rẹ? Ranti ijọ enia rẹ ti iwọ ti rà nigba atijọ; ilẹ-ini rẹ ti iwọ ti rà pada; òke Sioni yi, ninu eyi ti iwọ ngbe. Gbé ẹsẹ rẹ soke si ahoro lailai nì; ani si gbogbo eyiti ọta ti fi buburu ṣe ni ibi-mimọ́. Awọn ọta rẹ nke ramu-ramu lãrin ijọ enia rẹ; nwọn gbé asia wọn soke fun àmi. Nwọn dabi ọkunrin ti ngbé akeke rẹ̀ soke ninu igbo didi, Ṣugbọn nisisiyi iṣẹ ọnà finfin ni nwọn fi akeke ati òlu wó lulẹ pọ̀ li ẹ̃kan. Nwọn tinabọ ibi-mimọ́ rẹ, ni wiwo ibujoko orukọ rẹ lulẹ, nwọn sọ ọ di ẽri. Nwọn wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a run wọn pọ̀: nwọn ti kun gbogbo ile Ọlọrun ni ilẹ na. Awa kò ri àmi wa: kò si woli kan mọ́: bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi yio ti pẹ to. Ọlọrun, ọta yio ti kẹgan pẹ to? ki ọta ki o ha ma sọ̀rọ òdi si orukọ rẹ lailai? Ẽṣe ti iwọ fi fa ọwọ rẹ sẹhin, ani ọwọ ọtún rẹ? fà a yọ jade kuro li õkan aiya rẹ ki o si pa a run. Nitori Ọlọrun li Ọba mi li atijọ wá, ti nṣiṣẹ igbala lãrin aiye. Iwọ li o ti yà okun ni meji nipa agbara rẹ: iwọ ti fọ́ ori awọn erinmi ninu omi. Iwọ fọ́ ori Lefiatani tũtu, o si fi i ṣe onjẹ fun awọn ti ngbe inu ijù. Iwọ là orisun ati iṣan-omi: iwọ gbẹ awọn odò nla. Tirẹ li ọsán, tirẹ li oru pẹlu: iwọ li o ti pèse imọlẹ ati õrun. Iwọ li o ti pàla eti aiye: iwọ li o ṣe igba ẹ̀run ati igba otutu. Ranti eyi, Oluwa, pe ọta nkẹgàn, ati pe awọn enia buburu nsọ̀rọ odi si orukọ rẹ. Máṣe fi ọkàn àdaba rẹ le ẹranko igbẹ lọwọ: máṣe gbagbe ijọ awọn talaka rẹ lailai. Juba majẹmu nì: nitori ibi òkunkun aiye wọnni o kún fun ibugbe ìka. Máṣe jẹ ki ẹniti a ni lara ki o pada ni ìtiju; jẹ ki talaka ati alaini ki o yìn orukọ rẹ. Ọlọrun, dide, gbà ẹjọ ara rẹ rò: ranti bi aṣiwere enia ti ngàn ọ lojojumọ. Máṣe gbagbe ohùn awọn ọta rẹ: irọkẹ̀kẹ awọn ti o dide si ọ npọ̀ si i nigbagbogbo.