O. Daf 70:4-5
O. Daf 70:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki gbogbo awọn ti nwá ọ ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn nipa tirẹ: ki iru awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Ki a gbé Ọlọrun ga! Ṣugbọn talaka ati alaini li emi: Ọlọrun, yara si mi: iwọ li oluranlọwọ ati olugbala mi: Oluwa, máṣe pẹ́ titi.
O. Daf 70:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ, kí inú wọn sì máa dùn, kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé, “Ọlọrun tóbi!” Ṣugbọn ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí, yára wá sọ́dọ̀ mi, Ọlọrun! Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi ati olùgbàlà mi, má pẹ́ OLÚWA.
O. Daf 70:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀ kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ, kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé, “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!” Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní; wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi; OLúWA, má ṣe dúró pẹ́.