O. Daf 70:1-5
O. Daf 70:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, yara gbà mi; Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ. Ki oju ki o tì awọn ti nwá ọkàn mi, ki nwọn ki o si dãmu: ki nwọn ki o si pada sẹhin, ki a si dãmu awọn ti nwá ifarapa mi. Ki a pa wọn li ẹhìn dà fun ère itiju awọn ti nwi pe, A! a! Ki gbogbo awọn ti nwá ọ ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn nipa tirẹ: ki iru awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Ki a gbé Ọlọrun ga! Ṣugbọn talaka ati alaini li emi: Ọlọrun, yara si mi: iwọ li oluranlọwọ ati olugbala mi: Oluwa, máṣe pẹ́ titi.
O. Daf 70:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun, dákun, gbà mí, yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọn fẹ́ gba ẹ̀mí mi kí ìdàrúdàpọ̀ bá wọn; jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn, kí wọn sì tẹ́. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bo àwọn tí ń yọ̀ mí, tí ń ṣe jàgínní mi; kí wọn sì gba èrè ìtìjú. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ, kí inú wọn sì máa dùn, kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé, “Ọlọrun tóbi!” Ṣugbọn ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí, yára wá sọ́dọ̀ mi, Ọlọrun! Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi ati olùgbàlà mi, má pẹ́ OLÚWA.
O. Daf 70:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là, OLúWA, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́. Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú; kí àwọn tó ń wá ìparun mi yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú. Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!” Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀ kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ, kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé, “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!” Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní; wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi; OLúWA, má ṣe dúró pẹ́.