O. Daf 7:1-5
O. Daf 7:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, Ọlọrun mi, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: gbà mi lọwọ gbogbo awọn ti nṣe inunibini si mi, ki o si yọ mi kuro. Ki o má ba fa ọkàn mi ya bi kiniun, a yà a pẹrẹpẹrẹ, nigbati kò si oluranlọwọ. Oluwa, Ọlọrun mi, bi mo ba ṣe eyi, bi ẹ̀ṣẹ ba mbẹ li ọwọ mi; Bi mo ba fi ibi san a fun ẹniti temi tirẹ̀ wà li alafia; (nitõtọ ẹniti nṣe ọta mi li ainidi, emi tilẹ gbà a là:) Jẹ ki ọta ki o ṣe inunibini si ọkàn mi, ki o si mu u; ki o tẹ̀ ẹmi mi mọlẹ, ki o si fi ọlá mi le inu ekuru.
O. Daf 7:1-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di; gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi. Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun, kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀. OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí, bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi, bí mo bá fi ibi san án fún olóore, tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí, jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá, kí ó tẹ̀ mí pa, kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
O. Daf 7:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ; gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi, kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún, wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí. OLúWA Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí: Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi; jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀ kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela.