O. Daf 69:1-18

O. Daf 69:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbà mí, Ọlọ́run, nítorí omi ti kún dé ọrùn mi. Mo ń rì nínú irà jíjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jíjìn; ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀. Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi. Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí wọ́n ju irun orí mi; lọ púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí, àwọn tí ń wá láti pa mí run A fi ipá mú mi láti san ohun tí èmi kò jí. Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run; ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ. Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi, Olúwa, OLúWA àwọn ọmọ-ogun; Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi, Ọlọ́run Israẹli. Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn, ìtìjú sì bo ojú mi. Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi; àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi; Nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run, àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí. Nígbà tí mo sọkún tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù; Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà, àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi. Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi, mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí OLúWA, ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ, dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú. Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀, Má ṣe jẹ́ kí n rì; gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, kúrò nínú ibú omi. Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi. Dá mí lóhùn, OLúWA, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ; nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ: yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú. Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là; rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.

O. Daf 69:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌLỌRUN, gbà mi; nitoriti omi wọnni wọ̀ inu lọ si ọkàn mi. Emi rì ninu irà jijin, nibiti ibuduro kò si, emi de inu omi jijin wọnni, nibiti iṣan-omi ṣàn bò mi lori. Agara ẹkun mi da mi: ọfun mi gbẹ: oju kún mi nigbati emi duro de Ọlọrun mi. Awọn ti o korira mi lainidi jù irun ori mi lọ: awọn ti nṣe ọta mi laiṣẹ, ti iba pa mi run, nwọn lagbara: nigbana ni mo san ohun ti emi kò mu. Ọlọrun, iwọ mọ̀ wère mi, ẹ̀ṣẹ mi kò si lumọ kuro loju rẹ. Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, máṣe jẹ ki oju ki o tì awọn ti o duro de ọ nitori mi: máṣe jẹ ki awọn ti nwá ọ ki o damu nitori mi, Ọlọrun Israeli. Nitoripe nitori tirẹ li emi ṣe nrù ẹ̀gan; itiju ti bo mi loju. Emi di àjeji si awọn arakunrin mi, ati alejo si awọn ọmọ iya mi. Nitori ti itara ile rẹ ti jẹ mi tan; ati ẹ̀gan awọn ti o gàn ọ, ṣubu lù mi. Nigbati mo sọkun, ti mo si nfi àwẹ jẹ ara mi ni ìya, eyi na si di ẹ̀gan mi. Emi fi aṣọ ọ̀fọ sẹ aṣọ mi pẹlu: mo si di ẹni-owe fun wọn. Awọn ti o joko li ẹnu-bode nsọ̀rọ si mi; emi si di orin awọn ọmuti. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, iwọ li emi ngbadura mi si, Oluwa, ni igba itẹwọgba: Ọlọrun, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ da mi lohùn, ninu otitọ igbala rẹ. Yọ mi kuro ninu ẹrẹ̀, má si ṣe jẹ ki emi ki o rì: gbigbà ni ki a gbà mi lọwọ awọn ti o korira mi, ati ninu omi jijìn wọnni. Máṣe jẹ ki kikún-omi ki o bò mi mọlẹ, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki ọgbun ki o gbé mi mì, ki o má si ṣe jẹ ki iho ki o pa ẹnu rẹ̀ de mọ́ mi. Oluwa, da mi lohùn; nitori ti iṣeun ifẹ rẹ dara, yipada si mi gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ irọnu ãnu rẹ. Ki o má si ṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara iranṣẹ rẹ: emi sa wà ninu ipọnju; yara, da mi lohùn. Sunmọ ọkàn mi, si rà a pada: gbà mi nitori awọn ọta mi.

O. Daf 69:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Gbà mí, Ọlọrun, nítorí omi ti mù mí dé ọrùn. Mo ti rì sinu irà jíjìn, níbi tí kò ti sí ohun ìfẹsẹ̀tẹ̀; mo ti bọ́ sinu ibú, omi sì ti bò mí mọ́lẹ̀. Mo sọkún títí àárẹ̀ mú mi, ọ̀nà ọ̀fun mi gbẹ, ojú mi sì di bàìbàì, níbi tí mo ti dúró, tí mò ń wo ojú ìwọ Ọlọrun mi. Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí pọ̀, wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ. Àwọn tí ó fẹ́ pa mí run lágbára. Àwọn ọ̀tá mi ń parọ́ mọ́ mi, àwọn nǹkan tí n kò jí ni wọ́n ní kí n fi dandan dá pada. Ọlọrun, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi, àwọn àṣìṣe mi kò sì fara pamọ́ fún ọ. Má tìtorí tèmi dójúti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, má sì tìtorí mi sọ àwọn tí ń wá ọ di ẹni àbùkù, Ọlọrun Israẹli. Nítorí tìrẹ ni mo ṣe di ẹni ẹ̀gàn, tí ìtìjú sì bò mí. Mo ti di àlejò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, mo sì di àjèjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá mi. Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún, ìwọ̀sí àwọn tí ó ń pẹ̀gàn rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀. Nígbà tí mo fi omijé gbààwẹ̀, ó di ẹ̀gàn fún mi. Nígbà tí mò ń wọ aṣọ ọ̀fọ̀, mo di ẹni àmúpòwe. Èmi ni àwọn tí ń jókòó lẹ́nu ibodè fi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ; àwọn ọ̀mùtí sì ń fi mí ṣe orin kọ. Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura sí ní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun, ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn. Yọ mí ninu irà yìí, má jẹ́ kí n rì, gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Má jẹ́ kí ìgbì omi bò mí mọ́lẹ̀, kí ibú omi má gbé mi mì, kí isà òkú má sì padé mọ́ mi. Dá mi lóhùn, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára; fojú rere wò mí, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ àánú rẹ. Má ṣe fi ojú pamọ́ fún èmi, iranṣẹ rẹ, nítorí tí mo wà ninu ìdààmú, yára dá mi lóhùn. Sún mọ́ mi, rà mí pada, kí o sì tú mi sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀tá mi!