O. Daf 57:7-11
O. Daf 57:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun, ọkàn mi ti mura: emi o kọrin, emi o si ma kọrin iyìn. Jí, iwọ ogo mi; jí, ohun-èlo orin ati duru: emi tikarami yio si jí ni kutukutu. Emi o ma yìn ọ, Oluwa lãrin awọn enia: emi o si ma kọrin si ọ lãrin awọn orilẹ-ède. Nitoriti ãnu rẹ pọ̀ de ọrun, ati otitọ rẹ de awọsanma. Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù awọn ọrun lọ ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.
O. Daf 57:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun, ọkàn mi dúró ṣinṣin! N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. Jí, ìwọ ọkàn mi! Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu, èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu. OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan; n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.
O. Daf 57:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run; ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn. Jí, ìwọ ọkàn mi! Jí, ohun orin èlò àti dùùrù! Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù. Èmi ó máa yìn ọ́, OLúWA, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn. Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run; òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀. Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ; kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.