O. Daf 55:12-14
O. Daf 55:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoriti kì iṣe ọta li o gàn mi: njẹ emi iba pa a mọra: bẹ̃ni kì iṣe ẹniti o korira mi li o gbé ara rẹ̀ ga si mi; njẹ emi iba fi ara mi pamọ́ kuro lọdọ rẹ̀: Ṣugbọn iwọ ni, ọkunrin ọ̀gba mi, amọ̀na mi, ati ojulumọ mi. Awa jumọ gbimọ didùn, awa si kẹgbẹ rìn wọ̀ ile Ọlọrun lọ.
O. Daf 55:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó bá ṣe pé ọ̀tá ní ń gàn mí, ǹ bá lè fara dà á. Bí ó bá ṣe pé ẹni tí ó kórìíra mi ní ń gbéraga sí mi, ǹ bá fara pamọ́ fún un. Ṣugbọn ìwọ ni; ìwọ tí o jẹ́ irọ̀ mi, alábàárìn mi, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́. À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí; a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun.
O. Daf 55:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi, èmi yóò fi ara mọ́ ọn; tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi, èmi ìbá sápamọ́ fún un. Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi, ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi, pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀, bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.