O. Daf 55:1-23

O. Daf 55:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

FETI si adura mi, Ọlọrun; má si ṣe fi ara rẹ pamọ kuro ninu ẹ̀bẹ mi. Fiye si mi, ki o si da mi lohùn: ara mi kò lelẹ ninu aroye mi, emi si npariwo; Nitori ohùn ọta nì, nitori inilara enia buburu: nitoriti nwọn mu ibi ba mi, ati ni ibinu, nwọn dẹkun fun mi. Aiya dùn mi gidigidi ninu mi: ipaiya ikú si ṣubu lù mi. Ibẹ̀ru ati ìwárìrì wá si ara mi, ati ibẹ̀ru ikú bò mi mọlẹ. Emi si wipe, A! iba ṣe pe emi ni iyẹ-apa bi àdaba! emi iba fò lọ, emi a si simi. Kiyesi i, emi iba rìn lọ si ọ̀na jijin rére, emi a si ma gbe li aginju. Emi iba yara sa asala mi kuro ninu ẹfufu lile ati iji na. Oluwa, ṣe iparun, ki o si yà wọn li ahọn: nitori ti mo ri ìwa agbara ati ijà ni ilu na. Ọsan ati oru ni nwọn fi nrìn odi rẹ̀ kiri: ìwa-ika pẹlu ati ikãnu mbẹ li arin rẹ̀. Ìwa buburu mbẹ li arin rẹ̀: ẹ̀tan ati eke kò kuro ni igboro rẹ̀. Nitoriti kì iṣe ọta li o gàn mi: njẹ emi iba pa a mọra: bẹ̃ni kì iṣe ẹniti o korira mi li o gbé ara rẹ̀ ga si mi; njẹ emi iba fi ara mi pamọ́ kuro lọdọ rẹ̀: Ṣugbọn iwọ ni, ọkunrin ọ̀gba mi, amọ̀na mi, ati ojulumọ mi. Awa jumọ gbimọ didùn, awa si kẹgbẹ rìn wọ̀ ile Ọlọrun lọ. Ki ikú ki o dì wọn mu, ki nwọn ki o si lọ lãye si isa-okú: nitori ti ìwa buburu mbẹ ni ibujoko wọn, ati ninu wọn. Bi o ṣe ti emi ni, emi o kepè Ọlọrun; Oluwa yio si gbà mi. Li alẹ, li owurọ, ati li ọsan, li emi o ma gbadura, ti emi o si ma kigbe kikan: on o si gbohùn mi. O ti gbà ọkàn mi silẹ li alafia lọwọ ogun ti o ti dó tì mi: nitoripe pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ni nwọn dide si mi. Ọlọrun yio gbọ́, yio si pọ́n wọn loju, ani ẹniti o ti joko lati igbani. Nitoriti nwọn kò ni ayipada, nwọn kò si bẹ̀ru Ọlọrun. O ti nà ọwọ rẹ̀ si iru awọn ti o wà li alafia pẹlu rẹ̀: o ti dà majẹmu rẹ̀. Ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ kunna jù ori-amọ lọ, ṣugbọn ogun jija li o wà li aiya rẹ̀: ọ̀rọ rẹ̀ kunna jù ororo lọ, ṣugbọn idà fifayọ ni nwọn. Kó ẹrù rẹ lọ si ara Oluwa, on ni yio si mu ọ duro: on kì yio jẹ ki ẹsẹ olododo ki o yẹ̀ lai. Ṣugbọn iwọ, Ọlọrun, ni yio mu wọn sọkalẹ lọ si iho iparun: awọn enia ẹ̀jẹ ati enia ẹ̀tan kì yio pe àbọ ọjọ wọn; ṣugbọn emi o gbẹkẹle ọ.

O. Daf 55:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Tẹ́tí sí adura mi, Ọlọrun, má sì fara pamọ́ nígbà tí mo bá ń bẹ̀bẹ̀. Fetí sí mi, kí o sì dá mi lóhùn; ìṣòro ti borí mi. Ìhàlẹ̀ ọ̀tá bà mí ninu jẹ́, nítorí ìnilára àwọn eniyan burúkú; wọ́n kó ìyọnu bá mi, wọ́n ń bínú mi, inú wọn sì dùn láti máa bá mi ṣọ̀tá. Ọkàn mi wà ninu ìrora, ìpayà ikú ti dé bá mi. Ẹ̀rù ati ìwárìrì dà bò mí, ìpayà sì bò mí mọ́lẹ̀. Mo ní, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Ǹ bá fò lọ, ǹ bá lọ sinmi. Áà! Ǹ bá lọ jìnnà réré, kí n lọ máa gbé inú ijù; ǹ bá yára lọ wá ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ líle ati ìjì.” Da èrò wọn rú, OLUWA, kí o sì dà wọ́n lédè rú; nítorí ìwà ipá ati asọ̀ pọ̀ ninu ìlú. Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń yí orí odi rẹ̀ ká; ìwà ìkà ati ìyọnu ni ó sì pọ̀ ninu rẹ̀. Ìparun wà ninu rẹ̀; ìnilára ati ìwà èrú kò sì kúrò láàrin ìgboro rẹ̀. Bí ó bá ṣe pé ọ̀tá ní ń gàn mí, ǹ bá lè fara dà á. Bí ó bá ṣe pé ẹni tí ó kórìíra mi ní ń gbéraga sí mi, ǹ bá fara pamọ́ fún un. Ṣugbọn ìwọ ni; ìwọ tí o jẹ́ irọ̀ mi, alábàárìn mi, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́. À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí; a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun. Jẹ́ kí ikú jí àwọn ọ̀tá mi pa; kí wọ́n lọ sinu isà òkú láàyè; kí wọ́n wọ ibojì lọ pẹlu ìpayà. Ṣugbọn èmi ké pe Ọlọrun; OLUWA yóo sì gbà mí. Mò ń ráhùn tọ̀sán-tòru, mo sì ń kérora; OLUWA óo gbọ́ ohùn mi. Yóo yọ mí láìfarapa, ninu ogun tí mò ń jà, nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí wọ́n dojú kọ mí, tí wọn ń bá mi jà. Ọlọrun tí ó gúnwà láti ìgbàanì yóo gbọ́, yóo sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí pé wọn kò pa ìwà wọn dà, wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọrun. Alábàárìn mi gbógun ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó yẹ àdéhùn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn ju oyin lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìjà ni ó wà lọ́kàn rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ tutù ju omi àmù lọ, ṣugbọn idà aṣekúpani ni. Kó gbogbo ìṣòro rẹ lé OLUWA lọ́wọ́, yóo sì gbé ọ ró; kò ní jẹ́ kí á ṣí olódodo ní ipò pada. Ṣugbọn ìwọ, Ọlọrun, o óo sọ àwọn apani ati àwọn alárèékérekè, sinu kòtò ìparun; wọn kò ní lo ìdajì ọjọ́ ayé wọn. Ṣugbọn èmi óo gbẹ́kẹ̀lé ọ.

O. Daf 55:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run, Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́: Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn. Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo. Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni, nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú; nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi, wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn. Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú; ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi. Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi; ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀. Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi. Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré, kí ń sì dúró sí aginjù; Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò, jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.” Da àwọn ẹni búburú láàmú, OLúWA, da ahọ́n wọn rú, nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà. Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri; ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀. Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀; ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀. Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi, èmi yóò fi ara mọ́ ọn; tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi, èmi ìbá sápamọ́ fún un. Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi, ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi, pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀, bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run. Kí ikú kí ó dé bá wọn, Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú, Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà, nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn. Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run; OLúWA yóò sì gbà mí. Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú, o sì gbọ́ ohùn mi. Ó rà mí padà láìléwu kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi. Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì— Sela. Nítorí tí wọn kò ní àyípadà, tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run. Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀; ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́, ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ, ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn. Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ OLúWA yóò sì mú ọ dúró; òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú. Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi wá sí ihò ìparun; Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn, kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.