O. Daf 50:7-11
O. Daf 50:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si sọ̀rọ; Israeli, emi o si jẹri si ọ: emi li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ. Emi kì yio ba ọ wi nitori ẹbọ rẹ, ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ wà niwaju mi nigbagbogbo. Emi kì yio mu akọ-malu lati ile rẹ jade, tabi obukọ ninu agbo-ẹran rẹ: Nitori gbogbo ẹran igbo ni ti emi, ati ẹrankẹran lori ẹgbẹrun òke. Emi mọ̀ gbogbo ẹiyẹ awọn oke nla: ati ẹranko igbẹ ni ti emi.
O. Daf 50:7-11 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, n óo sọ̀rọ̀, Israẹli, n óo takò yín. Èmi ni Ọlọrun, Ọlọrun yín. N kò ba yín wí nítorí ẹbọ rírú; nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń rú ẹbọ sísun sí mi. N kò ní gba akọ mààlúù lọ́wọ́ yín, tabi òbúkọ láti agbo ẹran yín. Nítorí èmi ni mo ni gbogbo ẹran inú igbó, tèmi sì ni gbogbo mààlúù tó wà lórí ẹgbẹrun òkè. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ni mo mọ̀, tèmi sì ni gbogbo nǹkan tí ń rìn ninu pápá.
O. Daf 50:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ: èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ. Èmi kí yóò bá ọ wí nítorí àwọn ìrúbọ rẹ, tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi ní ìgbà gbogbo. Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un, tàbí kí o mú òbúkọ láti inú agbo ẹran rẹ̀ Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè. Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi