O. Daf 50:10-15
O. Daf 50:10-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori gbogbo ẹran igbo ni ti emi, ati ẹrankẹran lori ẹgbẹrun òke. Emi mọ̀ gbogbo ẹiyẹ awọn oke nla: ati ẹranko igbẹ ni ti emi. Bi ebi npa mi, emi kì yio sọ fun ọ: nitori pe aiye ni ti emi, ati ẹkún inu rẹ̀. Emi o ha jẹ ẹran malu, tabi emi a ma mu ẹ̀jẹ ewurẹ bi? Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjẹ́ rẹ fun Ọga-ogo. Ki o si kepè mi ni ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yìn mi logo.
O. Daf 50:10-15 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí èmi ni mo ni gbogbo ẹran inú igbó, tèmi sì ni gbogbo mààlúù tó wà lórí ẹgbẹrun òkè. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ni mo mọ̀, tèmi sì ni gbogbo nǹkan tí ń rìn ninu pápá. “Bí ebi bá tilẹ̀ pa mí, ẹ̀yin kọ́ ni n óo sọ fún, nítorí èmi ni mo ni gbogbo ayé ati àwọn nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀. Ṣé èmi a máa jẹ ẹran akọ mààlúù? Àbí mà máa mu ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́? Ọpẹ́ ni kí ẹ fi rúbọ sí Ọlọrun, kí ẹ sì máa san ẹ̀jẹ́ yín fún Ọ̀gá Ògo. Ẹ ké pè mí ní ọjọ́ ìṣòro; n óo gbà yín, ẹ óo sì yìn mí lógo.”
O. Daf 50:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè. Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ, nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo tí ó wa ní inú rẹ̀. Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ? “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run, kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo. Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú, èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”