O. Daf 44:1-8
O. Daf 44:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun, a ti fi etí wa gbọ́, àwọn baba wa sì ti sọ fún wa, nípa àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn, àní, ní ayé àtijọ́: Ìwọ ni o fi ọwọ́ ara rẹ lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún wọn, tí o sì fi ẹsẹ̀ àwọn baba wa múlẹ̀; o fi ìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè náà, o sì jẹ́ kí ó dára fún àwọn baba wa. Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà, kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun; agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ati ojurere rẹ; nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn. Ìwọ ni Ọba mi ati Ọlọrun mi; ìwọ ni o fi àṣẹ sí i pé kí Jakọbu ó ṣẹgun. Nípa agbára rẹ ni a fi bi àwọn ọ̀tá wa sẹ́yìn, orúkọ rẹ ni a fi tẹ àwọn tí ó gbógun tì wá mọ́lẹ̀. Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo gbẹ́kẹ̀lé; idà mi kò sì le gbà mí. Ṣugbọn ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, o sì dójú ti àwọn tí ó kórìíra wa. Ìwọ Ọlọrun ni a fi ń yangàn nígbà gbogbo; a óo sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí lae.
O. Daf 44:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, awa ti fi eti wa gbọ́, awọn baba wa si ti sọ fun wa ni iṣẹ́ nla ti iwọ ṣe li ọjọ wọn, ni igbà àtijọ́. Bi iwọ ti fi ọwọ rẹ lé awọn keferi jade, ti iwọ si gbin wọn: bi iwọ ti fõró awọn enia na, ti iwọ si mu wọn gbilẹ. Nitoriti nwọn kò ni ilẹ na nipa idà ara wọn, bẹ̃ni kì iṣe apá wọn li o gbà wọn; bikoṣe ọwọ ọtún rẹ ati apá rẹ, ati imọlẹ oju rẹ, nitoriti iwọ ni ifẹ rere si wọn. Iwọ li Ọba mi, Ọlọrun: paṣẹ igbala fun Jakobu. Nipasẹ̀ rẹ li awa o bì awọn ọta wa ṣubu: nipasẹ orukọ rẹ li awa o tẹ̀ awọn ti o dide si wa mọlẹ. Nitoriti emi kì yio gbẹkẹle ọrun mi, bẹ̃ni idà mi kì yio gbà mi. Ṣugbọn iwọ li o ti gbà wa lọwọ awọn ọta wa, iwọ si ti dojutì awọn ti o korira wa. Niti Ọlọrun li awa nkọrin iyìn li ọjọ gbogbo, awa si nyìn orukọ rẹ lailai.
O. Daf 44:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run àwọn baba wa tí sọ fún wa ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn, ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn. Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde Ìwọ sì gbin àwọn baba wa; Ìwọ run àwọn ènìyàn náà Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀. Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ; àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn. Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu. Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú; nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀ Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá, Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa, ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa. Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́, àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.