O. Daf 37:3-6
O. Daf 37:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ. Ṣe inu-didùn si Oluwa pẹlu, on o si fi ifẹ inu rẹ̀ fun ọ. Fi ọ̀na rẹ̀ le Oluwa lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ. Yio si mu ododo rẹ jade bi imọlẹ, ati idajọ rẹ bi ọsángangan.
O. Daf 37:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere. Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́. Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́. Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ. Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀; ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan.
O. Daf 37:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀. Ṣe inú dídùn sí OLúWA; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀. Fi ọ̀nà rẹ lé OLúWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é. Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.