O. Daf 37:23-28
O. Daf 37:23-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
A ṣe ìlana ẹsẹ enia lati ọwọ Oluwa wá: o si ṣe inu didùn si ọ̀na rẹ̀. Bi o tilẹ ṣubu, a kì yio ta a nù kuro patapata; nitoriti Oluwa di ọwọ rẹ̀ mu. Emi ti wà li ewe, emi si dagba; emi kò ti iri ki a kọ̀ olododo silẹ, tabi ki iru-ọmọ rẹ̀ ki o ma ṣagbe onjẹ. Alãnu li on nigbagbogbo, a ma wín ni: a si ma busi i fun iru-ọmọ rẹ̀. Kuro ninu ibi ki o si ma ṣe rere; ki o si ma joko lailai. Nitoriti Oluwa fẹ idajọ, kò si kọ̀ awọn enia mimọ́ rẹ̀ silẹ; a si pa wọn mọ́ lailai: ṣugbọn iru-ọmọ awọn enia buburu li a o ke kuro.
O. Daf 37:23-28 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni; a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé, nítorí OLUWA yóo gbé e ró. Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà: n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀, tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ. Olódodo ní ojú àánú, a sì máa yáni ní nǹkan, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere; kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae. Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́; kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀. Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae, ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run.
O. Daf 37:23-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá, o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀; Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí OLúWA di ọwọ́ rẹ̀ mú. Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ. Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni; a sì máa bùsi i fún ni. Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere; nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé. Nítorí pé OLúWA fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.