O. Daf 37:1-7
O. Daf 37:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
MÁṢE ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutù. Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ. Ṣe inu-didùn si Oluwa pẹlu, on o si fi ifẹ inu rẹ̀ fun ọ. Fi ọ̀na rẹ̀ le Oluwa lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ. Yio si mu ododo rẹ jade bi imọlẹ, ati idajọ rẹ bi ọsángangan. Iwọ simi ninu Oluwa, ki o si fi sũru duro dè e; máṣe ikanra nitori ẹniti o nri rere li ọ̀na rẹ̀, nitori ọkunrin na ti o nmu èro buburu ṣẹ.
O. Daf 37:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú; má sì jowú àwọn aṣebi; nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko; wọn óo sì rọ bí ewé. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere. Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́. Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́. Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ. Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀; ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún; tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é.
O. Daf 37:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko, wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù. Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀. Ṣe inú dídùn sí OLúWA; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀. Fi ọ̀nà rẹ lé OLúWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é. Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan. Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLúWA, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.